Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 32:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa li ọdun kẹwa Sedekiah, ọba Juda, eyiti o jẹ ọdun kejidilogun ti Nebukadnessari.

2. Nigbana ni ogun ọba Babeli ha Jerusalemu mọ: a si se Jeremiah woli mọ agbala ile túbu, ti o wà ni ile ọba Juda.

3. Nitori Sedekiah, ọba Judah, ti se e mọ, wipe, Ẽṣe ti iwọ sọtẹlẹ, ti o si wipe, Bayi li Oluwa wi, wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ ọba Babeli, on o si ko o;

4. Ati Sedekiah, ọba Juda, kì yio bọ́ li ọwọ awọn ara Kaldea, ṣugbọn a o fi i le ọwọ ọba Babeli, Lõtọ, yio si ba a sọ̀rọ li ojukoju, oju rẹ̀ yio si ri oju rẹ̀.

5. On o si mu Sedekiah lọ si Babeli, nibẹ ni yio si wà titi emi o fi bẹ̀ ẹ wò, li Oluwa wi; bi ẹnyin tilẹ ba awọn ará Kaldea jà, ẹnyin kì yio ṣe rere.

6. Jeremiah si wipe, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,

7. Wò o, Hanameeli, ọmọ Ṣallumu, ẹ̀gbọn rẹ, yio tọ̀ ọ wá, wipe, Iwọ rà oko mi ti o wà ni Anatoti: nitori titọ́ irasilẹ jẹ tirẹ lati rà a.

8. Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, si tọ̀ mi wá li agbala ile túbu gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, o si wi fun mi pe, Jọ̃, ra oko mi, ti o wà ni Anatoti, ti o wà ni ilẹ Benjamini: nitori titọ́ ogun rẹ̀ jẹ tirẹ, ati irasilẹ jẹ tirẹ; rà a fun ara rẹ. Nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi li ọ̀rọ Oluwa.

9. Emi si rà oko na lọwọ Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, ti o wà ni Anatoti, mo si wọ̀n owo fun u, ṣekeli meje ati ìwọn fadaka mẹwa.

10. Mo si kọ ọ sinu iwe, mo si di i, mo si pè awọn ẹlẹri si i, mo si wọ̀n owo na ninu òṣuwọn.

11. Mo si mu iwe rirà na eyiti a dí nipa aṣẹ ati ilana, ati eyiti a ṣi silẹ.

12. Mo si fi iwe rirà na fun Baruki, ọmọ Neriah, ọmọ Masseiah, li oju Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, ati niwaju awọn ẹlẹri ti o kọ orukọ wọn si iwe rirà na, niwaju gbogbo ọkunrin Juda ti o joko ni àgbala ile túbu.

13. Mo si paṣẹ fun Baruki li oju wọn wipe,

14. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wipe, Mu iwe wọnyi, iwe rirà yi, ti a dí, ati iwe yi ti a ṣi silẹ; ki o si fi wọn sinu ikoko, ki nwọn ki o le wà li ọjọ pupọ.

Ka pipe ipin Jer 32