Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 31:8-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Wò o, emi o mu wọn lati ilẹ ariwa wá, emi o si kó wọn jọ lati àgbegbe ilẹ aiye, afọju ati ayarọ pẹlu wọn, aboyun ati ẹniti nrọbi ṣọkan pọ̀: li ẹgbẹ nlanla ni nwọn o pada sibẹ.

9. Nwọn o wá pẹlu ẹkun, pẹlu adura li emi o si ṣe amọ̀na wọn: emi o mu wọn rìn lẹba odò omi li ọ̀na ganran, nwọn kì yio kọsẹ ninu rẹ̀: nitori emi jẹ baba fun Israeli, Efraimu si li akọbi mi.

10. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin orilẹ-ède, ẹ sọ ọ ninu erekuṣu òkere, ki ẹ si wipe, Ẹniti o tú Israeli ka yio kó o jọ, yio si pa a mọ, gẹgẹ bi oluṣọ-agutan agbo-ẹran rẹ̀.

11. Nitori Oluwa ti tú Jakobu silẹ, o si rà a pada li ọwọ awọn ti o li agbara jù u lọ.

12. Njẹ, nwọn o wá, nwọn o si kọrin ni ibi giga Sioni, nwọn o si jumọ lọ sibi ore Oluwa, ani fun alikama, ati fun ọti-waini, ati fun ororo, ati fun ẹgbọrọ agbo-ẹran, ati ọwọ́-ẹran: ọkàn wọn yio si dabi ọgbà ti a bomi rin; nwọn kì yio si kãnu mọ rara.

13. Nigbana ni wundia yio yọ̀ ninu ijó, pẹlu ọdọmọkunrin ati arugbo ṣọkan pọ̀: nitori emi o sọ ọ̀fọ wọn di ayọ̀, emi o si tù wọn ninu, emi o si mu wọn yọ̀ lẹhin ikãnu wọn.

14. Emi o si fi sisanra tẹ ọkàn awọn alufa lọrun, ore mi yio si tẹ awọn enia mi lọrun, li Oluwa wi.

15. Bayi li Oluwa wi, Ni Rama li a gbọ́ ohùnrere, ẹkún kikoro; Rakeli nsọkun fun awọn ọmọ rẹ̀, kò gbipẹ nitori awọn ọmọ rẹ̀, nitoripe nwọn kò si.

16. Bayi li Oluwa wi; Dá ohùn rẹ duro ninu ẹkun, ati oju rẹ ninu omije: nitori iṣẹ rẹ ni ère, li Oluwa wi, nwọn o si pada wá lati ilẹ ọta.

17. Ireti si wà ni igbẹhin rẹ, li Oluwa wi, pe awọn ọmọ rẹ yio pada si agbegbe wọn.

18. Lõtọ emi ti gbọ́ Efraimu npohùnrere ara rẹ̀ bayi pe; Iwọ ti nà mi, emi si di ninà, bi ọmọ-malu ti a kò kọ́; yi mi pada, emi o si yipada; nitori iwọ li Oluwa Ọlọrun mi.

Ka pipe ipin Jer 31