Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 28:2-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Emi ti ṣẹ àjaga ọba Babeli.

3. Ninu akoko ọdun meji li emi o tun mu gbogbo ohun-èlo ile Oluwa pada wá si ibi yi, ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kó kuro ni ibi yi, ti o si mu wọn lọ si Babeli.

4. Emi o si tun mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, pẹlu awọn igbekun Juda, ti o ti lọ si Babeli pada wá si ibi yi, li Oluwa wi, nitori emi o si ṣẹ àjaga ọba Babeli.

5. Jeremiah woli si wi fun Hananiah woli niwaju awọn alufa ati niwaju gbogbo enia, ti o duro ni ile Oluwa pe:

6. Jeremiah woli si wipe, Amin: ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃: ki Oluwa ki o mu ọ̀rọ rẹ ti iwọ sọ asọtẹlẹ ṣẹ, lati mu ohun-elo ile Oluwa ati gbogbo igbekun pada, lati Babeli wá si ibi yi.

Ka pipe ipin Jer 28