Jeremiah woli si wipe, Amin: ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃: ki Oluwa ki o mu ọ̀rọ rẹ ti iwọ sọ asọtẹlẹ ṣẹ, lati mu ohun-elo ile Oluwa ati gbogbo igbekun pada, lati Babeli wá si ibi yi.