Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 23:25-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Emi ti gbọ́ eyiti awọn woli sọ, ti nwọn sọ asọtẹlẹ li orukọ mi wi pe, Mo lá alá! mo lá alá!

26. Yio ti pẹ to, ti eyi yio wà li ọkàn awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ eke? ani, awọn alasọtẹlẹ ẹ̀tan ọkàn wọn.

27. Ti nwọn rò lati mu ki enia mi ki o gbàgbe orukọ mi nipa alá wọn ti nwọn nrọ́, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀, gẹgẹ bi awọn baba wọn ti gbagbe orukọ mi nitori Baali.

28. Woli na ti o lála, jẹ ki o rọ́ ọ; ati ẹniti o ni ọ̀rọ mi, jẹ ki o fi ododo sọ ọ̀rọ mi. Kini iyangbo ni iṣe ninu ọkà, li Oluwa wi?

29. Ọ̀rọ mi kò ha dabi iná? li Oluwa wi; ati bi òlu irin ti nfọ́ apata tútu?

30. Nitorina sa wò o, emi dojukọ awọn woli, li Oluwa wi, ti o nji ọ̀rọ mi, ẹnikini lati ọwọ ẹnikeji rẹ̀.

31. Sa wò o, emi o dojukọ awọn woli, li Oluwa wi, ti nwọn lò ahọn wọn, ti nwọn nsọ jade pe: O wi.

32. Sa wò o, emi dojukọ awọn ti o nsọ asọtẹlẹ alá èke, li Oluwa wi, ti nwọn si nrọ́ wọn, ti nwọn si mu enia mi ṣìna nipa eke wọn, ati nipa iran wọn: ṣugbọn emi kò rán wọn, emi kò si paṣẹ fun wọn: nitorina, nwọn kì yio ràn awọn enia yi lọwọ rara, li Oluwa wi.

33. Ati nigbati awọn enia yi, tabi woli, tabi alufa, yio bi ọ lere wipe, kini Ọ̀rọ-wuwo Oluwa? nigbana ni iwọ o wi fun wọn Ọ̀rọ-wuwo ni eyi pé: Emi o tì nyin jade, li Oluwa wi.

34. Ati woli, ati alufa, ati awọn enia, ti yio wipe, Ọ̀rọ-wuwo Oluwa, emi o jẹ oluwa rẹ̀ ati ile rẹ̀ ni ìya.

35. Bayi li ẹnyin o wi, ẹnikini fun ẹnikeji, ati ẹnikan fun arakunrin rẹ̀, pe Kini idahùn Oluwa? ati kini ọ̀rọ Oluwa?

36. Ẹ kì o si ranti ọ̀rọ-wuwo Oluwa mọ́, nitori ọ̀rọ olukuluku yio di ẹrù-wuwo fun ontikararẹ̀; nitori ti ẹnyin ti yi ọ̀rọ Ọlọrun alãye dà, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun wa.

37. Bayi ni iwọ o wi fun woli nì pe: Idahùn wo li Oluwa fi fun ọ? ati pẹlu; Kini Oluwa wi?

38. Ṣugbọn bi ẹnyin ba wipe, ọ̀rọ-wuwo Oluwa, nitorina, bayi li Oluwa wi, nitori ẹnyin nsọ ọ̀rọ yi pe, ọ̀rọ-wuwo Oluwa ti emi si ranṣẹ si nyin pe ki ẹ máṣe wipe: ọ̀rọ-wuwọ Oluwa;

39. Nitorina, sa wò o, Emi o gbagbe nyin patapata, emi o si kọ̀ nyin silẹ, emi o si tì nyin jade, ati ilu ti mo fi fun nyin ati fun awọn baba nyin, kuro niwaju mi.

40. Emi o si mu ẹ̀gan ainipẹkun wá sori nyin, ati itiju lailai, ti a kì yio gbagbe.

Ka pipe ipin Jer 23