Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 17:16-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Bi o ṣe ti emi ni, emi kò yara kuro ki emi má ṣe oluṣọ-agutan, lẹhin rẹ, bẹ̃ni emi kò bere ọjọ ipọnju, iwọ mọ̀: eyiti o jade li ète mi, o ti hàn niwaju rẹ.

17. Máṣe di ibẹ̀ru fun mi! iwọ ni ireti mi li ọjọ ibi!

18. Jẹ ki oju ki o tì awọn ti o nṣe inunibini si mi, ṣugbọn má jẹ ki oju ki o tì mi: jẹ ki nwọn ki o dãmu, ṣugbọn máṣe jẹ ki emi ki o dãmu: mu ọjọ ibi wá sori wọn, ki o si fi iparun iṣẹpo meji pa wọn run.

19. Bayi li Oluwa wi fun mi; Lọ, ki o si duro ni ẹnu-ọ̀na awọn enia nibi ti awọn ọba Juda nwọle, ti nwọn si njade, ati ni gbogbo ẹnu-bode Jerusalemu.

20. Ki o si wi fun wọn pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda ati gbogbo Juda, ati gbogbo ẹnyin olugbe Jerusalemu, ti o nkọja ninu ẹnu-bode wọnyi.

21. Bayi li Oluwa wi, Ẹ kiyesi li ọkàn nyin, ki ẹ máṣe ru ẹrù li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe mu u wá ninu ẹnu-bode Jerusalemu:

22. Bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe gbe ẹrù jade kuro ninu ile nyin li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe iṣẹkiṣẹ, ṣugbọn ki ẹ yà ọjọ isimi si mimọ́, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun awọn baba nyin.

23. Ṣugbọn nwọn kò gbọ́, nwọn kò si tẹti silẹ, nwọn mu ọrun wọn le, ki nwọn ki o má ba gbọ́, ati ki nwọn o má bà gba ẹ̀kọ́.

24. Yio si ṣe bi ẹnyin ba tẹtisilẹ gidigidi si mi, li Oluwa wi, ti ẹ kò ba ru ẹrù kọja ni ẹnu-bode ilu yi li ọjọ isimi, ti ẹ ba si yà ọjọ isimi si mimọ, ti ẹ kò si ṣe iṣẹkiṣẹ ninu rẹ̀,

25. Nigbana ni nwọn o wọ ẹnu-bode ilu yi, ani ọba, ati ijoye ti o joko lori itẹ Dafidi, awọn ti ngun kẹ̀kẹ ati ẹṣin, awọn wọnyi pẹlu ijoye wọn, awọn ọkunrin Juda, ati olugbe Jerusalemu: nwọn o si ma gbe ilu yi lailai.

26. Nwọn o si wá lati ilu Juda wọnni, ati lati àgbegbe Jerusalemu yikakiri, ati lati ilẹ Benjamini, lati pẹtẹlẹ, ati lati oke, ati lati gusu wá, nwọn o si mu ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹran ati turari, ati awọn wọnyi ti o mu iyìn wá si ile Oluwa.

27. Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti emi, lati ya ọjọ isimi si mimọ́, ti ẹ kò si ru ẹrù, ti ẹ kò tilẹ wọ ẹnu-bode Jerusalemu li ọjọ isimi; nigbana ni emi o da iná ni ẹnu-bode wọnni, yio si jo ãfin Jerusalemu run, a kì o si pa a.

Ka pipe ipin Jer 17