Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jer 14:16-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ati awọn enia ti nwọn nsọ asọtẹlẹ fun ni a o lù bolẹ ni ita Jerusalemu, nitori ìyan ati idà, nwọn kì yio ri ẹniti o sin wọn, awọn aya wọn, ati ọmọkunrin wọn, ati ọmọbinrin wọn: nitoriti emi o tu ìwa-buburu wọn jade sori wọn.

17. Ki iwọ ki o si sọ ọ̀rọ yi fun wọn pe: oju mi sun omije li oru ati li ọsan, kì yio si dá, nitoriti a ti ṣa wundia ọmọbinrin enia mi li ọgbẹ nla kikoro gidigidi ni lilù na.

18. Bi emi ba jade lọ si papa, sa wò o, a ri awọn ti a fi idà pa! bi emi ba si wọ inu ilu lọ, sa wò o, awọn ti npa ọ̀kakà ikú nitori iyan! nitori awọn, ati awọn woli, ati awọn alufa nwọ́ lọ si ilẹ ti nwọn kò mọ̀.

19. Iwọ ha ti kọ̀ Juda silẹ patapata? ọkàn rẹ ti korira Sioni? ẽṣe ti iwọ ti lù wa, ti imularada kò si fun wa? awa nreti alafia, kò si si rere, ati fun igba imularada, ṣugbọn wò o, idãmu!

20. Awa jẹwọ iwa buburu wa, Oluwa, ati aiṣedede awọn baba wa: nitori awa ti ṣẹ̀ si ọ.

21. Máṣe korira wa, nitori orukọ rẹ, máṣe gan itẹ́ ogo rẹ, ranti, ki o máṣe dà majẹmu ti o ba wa dá.

22. Ẹniti o le mu ojo rọ̀ ha wà lọdọ awọn oriṣa awọn keferi? tabi ọrun le rọ̀ òjo? iwọ ha kọ́, Oluwa Ọlọrun wa? awa si nreti rẹ: nitori iwọ li o da gbogbo nkan wọnyi.

Ka pipe ipin Jer 14