Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 65:14-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Kiyesi i, awọn iranṣẹ mi yio kọrin fun inudidun, ṣugbọn ẹnyin o ke fun ibanujẹ ọkàn, ẹnyin o si hu fun irobinujẹ ọkàn.

15. Ẹnyin o si fi orukọ nyin silẹ fun egún fun awọn ayanfẹ mi: nitori Oluwa Jehofah yio pa ọ, yio si pè awọn iranṣẹ rẹ̀ li orukọ miran:

16. Ki ẹniti o fi ibukun fun ara rẹ̀ li aiye, ki o fi ibukun fun ara rẹ̀ ninu Ọlọrun otitọ; ẹniti o si mbura li aiye ki o fi Ọlọrun otitọ bura; nitori ti a gbagbe wahala iṣaju, ati nitoriti a fi wọn pamọ kuro loju mi.

17. Sa wò o, emi o da ọrun titun ati aiye titun: a kì yio si ranti awọn ti iṣaju, bẹ̃ni nwọn kì yio wá si aiya.

18. Ṣugbọn ki ẹnyin ki o yọ̀, ki inu nyin ki o si dùn titi lai ninu eyi ti emi o da: nitori kiyesi i, emi o da Jerusalemu ni inudidùn, ati awọn enia rẹ̀ ni ayọ̀.

19. Emi o si ṣe ariya ni Jerusalemu, emi o si yọ̀ ninu awọn enia mi: a kì yio si tun gbọ́ ohùn ẹkún mọ ninu rẹ̀, tabi ohùn igbe.

20. Ki yio si ọmọ-ọwọ nibẹ ti ọjọ rẹ̀ kì yio pẹ́, tabi àgba kan ti ọjọ rẹ̀ kò kún: nitori ọmọde yio kú li ọgọrun ọdun; ṣugbọn ẹlẹṣẹ ọlọgọrun ọdun yio di ẹni-ifibu.

21. Nwọn o si kọ ile, nwọn o si gbe inu wọn; nwọn o si gbìn ọgba àjara, nwọn o si jẹ eso wọn.

22. Nwọn kì yio kọ ile fun ẹlomiran lati gbé, nwọn kì yio gbìn fun ẹlomiran lati jẹ: nitori gẹgẹ bi ọjọ igi li ọjọ awọn enia mi ri, awọn ayanfẹ mi yio si jìfà iṣẹ ọwọ́ wọn.

23. Nwọn kì yio ṣiṣẹ lasan, nwọn kì yio bimọ fun wahala: nitori awọn ni iru alabukun Oluwa ati iru-ọmọ wọn pẹlu wọn.

24. Yio si ṣe, pe, ki nwọn ki o to pè, emi o dahùn; ati bi nwọn ba ti nsọ̀rọ lọwọ, emi o gbọ́.

25. Ikõko ati ọdọ-agutan yio jumọ jẹ pọ̀, kiniun yio si jẹ koriko bi akọ-mãlu: erupẹ ni yio jẹ onjẹ ejò. Nwọn kì yio panilara, tabi ki nwọn panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi, li Oluwa wi.

Ka pipe ipin Isa 65