Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 60:9-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nitõtọ erekuṣu wọnni yio duro dè mi, ọkọ Tarṣiṣi wọnni li ekini, lati mu awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti ọ̀na jìjin wá, fadaka wọn, ati wura wọn pẹlu wọn, fun orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ, ati fun Ẹni-Mimọ́ Israeli, nitoriti on ti ṣe ọ logo.

10. Awọn ọmọ alejo yio si mọ odi rẹ: awọn ọba wọn yio ṣe iranṣẹ fun ọ: nitori ni ìkannu mi ni mo lù ọ, ṣugbọn ni inu rere mi ni mo si ṣãnu fun ọ.

11. Nitori na awọn ẹnu-bodè rẹ yio ṣi silẹ nigbagbogbo; a kì yio se wọn lọsan tabi loru, ki a le mu ọla awọn Keferi wá sọdọ rẹ, ki a ba si mu awọn ọba wọn wá.

12. Nitori orilẹ-ède, tabi ilẹ ọba ti kì yio sin ọ, yio ṣegbe; orilẹ-ède wọnni li a o sọ dahoro raurau.

13. Ogo Lebanoni yio wá sọdọ rẹ, igi firi, igi pine, pẹlu igi boksi, lati ṣe ibi mimọ́ mi li ọṣọ; emi o ṣe ibi ẹsẹ mi logo.

14. Awọn ọmọkunrin awọn aninilara rẹ pẹlu yio wá ni itẹriba sọdọ rẹ; gbogbo awọn ti o ti ngàn ọ, nwọn o tẹ̀ ara wọn ba silẹ li atẹlẹsẹ rẹ; nwọn o si pe ọ ni Ilu Oluwa, Sioni ti Ẹni-Mimọ́ Israeli.

15. Ni bi a ti kọ̀ ọ silẹ, ti a si ti korira rẹ, tobẹ̃ ti ẹnikan kò kọja lãrin rẹ, emi o sọ ọ di ogo aiyeraiye, ayọ̀ iran-de-iran ọ̀pọlọpọ.

16. Iwọ o mu wàra awọn Keferi, iwọ o si mu ọmu awọn ọba; iwọ o si mọ̀ pe, emi Oluwa ni Olugbala rẹ, ati Olurapada rẹ, Ẹni-alagbara Jakobu.

17. Nipo idẹ emi o mu wura wá, nipo irin emi o mu fadaka wá, ati nipo igi, idẹ, ati nipo okuta, irin: emi o ṣe awọn ijoye rẹ ni alafia, ati awọn akoniṣiṣẹ́ rẹ ni ododo.

18. A kì yio gbọ́ ìwa-ipá mọ ni ilẹ rẹ, idahoro tabi iparun li agbègbe rẹ; ṣugbọn iwọ o pe odi rẹ ni Igbala, ati ẹnu-bodè rẹ ni Iyin.

19. Õrùn kì yio jẹ imọlẹ rẹ mọ li ọsan, bẹ̃ni oṣupa kì yio fi imọlẹ rẹ̀ ràn fun ọ; ṣugbọn Oluwa yio ṣe imọlẹ ainipẹkun rẹ, ati Ọlọrun rẹ ogo rẹ.

20. Õrùn rẹ ki yio wọ̀ mọ; bẹ̃ni oṣupa rẹ kì yio wọ̃kùn: nitori Oluwa yio jẹ imọlẹ ainipẹkun fun ọ, ọjọ ãwẹ̀ rẹ wọnni yio si de opin.

21. Ati awọn enia rẹ, gbogbo wọn o jẹ olododo: nwọn o jogun ilẹ na titi lailai, ẹka gbigbin mi, iṣẹ ọwọ́ mi, ki a ba le yìn mi logo.

22. Ẹni-kekere kan ni yio di ẹgbẹrun, ati kekere kan yio di alagbara orilẹ-ède: emi Oluwa yio ṣe e kankan li akokò rẹ̀.

Ka pipe ipin Isa 60