Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 58:5-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Ãwẹ̀ iru eyi ni mo yàn bi? ọjọ ti enia njẹ ọkàn rẹ̀ ni ìya? lati tẹ ori rẹ̀ ba bi koriko odo? ati lati tẹ́ aṣọ ọ̀fọ ati ẽru labẹ rẹ̀? iwọ o ha pe eyi ni ãwẹ̀, ati ọjọ itẹwọgba fun Oluwa?

6. Awẹ ti mo ti yàn kọ́ eyi? lati tú ọjá aiṣododo, lati tú ẹrù wiwo, ati lati jẹ ki anilara lọ lọfẹ, ati lati já gbogbo ajàga.

7. Kì ha ṣe lati fi onjẹ rẹ fun awọn ti ebi npa, ati ki iwọ ki o mu awọn otòṣi ti a tì sode wá si ile rẹ? nigbati iwọ ba ri arinhòho, ki iwọ ki o bò o, ki iwọ, ki o má si fi ara rẹ pamọ kuro lọdọ ẹran-ara tirẹ.

8. Nigbana ni imọlẹ rẹ yio bẹ́ jade bi owurọ, ilera rẹ yio sọ jade kánkán: ododo rẹ yio si lọ ṣaju rẹ; ogo Oluwa yio kó ọ jọ.

9. Nigbana ni iwọ o pè, Oluwa yio si dahun; iwọ o kigbe, on o si wipe, Emi nĩ. Bi iwọ ba mu àjaga, ninà ika, ati sisọ asan, kuro lãrin rẹ.

Ka pipe ipin Isa 58