Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 57:9-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Iwọ si ti lọ tiwọ ti ikunra sọdọ ọba, iwọ si ti sọ õrùn didùn rẹ di pupọ, iwọ si ti rán awọn ikọ̀ rẹ lọ jina réré, iwọ si ti rẹ̀ ara rẹ silẹ, ani si ipò okú.

10. Ãrẹ̀ mu ọ ninu jijìn ọ̀na rẹ: iwọ kò wipe, Ireti kò si: ìye ọwọ́ rẹ ni iwọ ti ri; nitorina ni inu rẹ kò ṣe bajẹ.

11. Ẹ̀ru tani mbà ọ ti o si nfòya, ti o nṣeke, ti iwọ kò si ranti mi tabi ki o kà a si? emi kò ha ti dakẹ ani lati igbãni wá, iwọ kò si bẹ̀ru mi?

12. Emi o fi ododo rẹ, ati iṣẹ rẹ hàn; nwọn kì o si gbè ọ.

13. Nigbati iwọ ba kigbe, jẹ ki awọn ẹgbẹ rẹ ki o gbà ọ; ṣugbọn ẹfũfu ni yio gbá gbogbo wọn lọ; emi yio mu wọn kuro: ṣugbọn ẹniti o ba gbẹkẹ rẹ̀ le mi yio ni ilẹ na, yio si jogun oke mimọ́ mi.

Ka pipe ipin Isa 57