Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 55:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ gbogbo ẹniti ongbẹ ngbẹ, ẹ wá sibi omi, ati ẹniti kò li owo; ẹ wá, ẹ rà, ki ẹ si jẹ; lõtọ, ẹ wá, ẹ rà ọti-waini ati wàra, laini owo ati laidiyele.

2. Nitori kini ẹ ṣe nná owo fun eyiti kì iṣe onjẹ? ati lãla nyin fun eyi ti kì itẹnilọrun? ni gbigbọ́, ẹ gbọ́ t'emi, ki ẹ si jẹ eyi ti o dara, si jẹ ki inu nyin dùn ninu ọra.

3. Ẹ tẹtilelẹ, ki ẹ si wá sọdọ mi: ẹ gbọ́, ọkàn nyin yio si yè: emi o si ba nyin dá majẹmu ainipẹkun, ãnu Dafidi ti o daju.

4. Kiye si i, emi ti fi on fun awọn enia fun ẹlẹri, olori ati alaṣẹ fun awọn enia.

5. Kiyesi i, iwọ o pe orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀, ati orilẹ-ède ti kò mọ̀ ọ yio sare wá sọdọ rẹ, nitori Oluwa Ọlọrun rẹ, ati nitori Ẹni-Mimọ Israeli; nitori on ti ṣe ọ li ogo.

Ka pipe ipin Isa 55