orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 52 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ọlọrun Yóo Gba Jerusalẹmu

1. JI! ji! gbe agbara rẹ wọ̀, iwọ Sioni; gbe aṣọ ogo rẹ wọ̀, iwọ Jerusalemu, ilu mimọ́: nitori lati igbayi lọ, alaikọla on alaimọ́ kì yio wọ̀ inu rẹ mọ.

2. Gbọ̀n ekuru kuro li ara rẹ, dide, joko, iwọ Jerusalemu: tú ọjá kuro li ọrùn rẹ, iwọ ondè ọmọbinrin Sioni.

3. Nitori bayi li Oluwa wi, a ti tà nyin lọfẹ, a o si rà nyin pada laisanwo.

4. Nitori bayi li Oluwa Jehofa wi, Awọn enia mi sọkalẹ lọ si Egipti li atijọ lati ṣe atipo nibẹ; ara Assiria si ni wọn lara lainidi.

5. Njẹ nisisiyi, Oluwa wipe, Kini mo nṣe nihin, ti a kó awọn enia mi lọ lọfẹ? awọn ti o jọba wọn mu nwọn kigbe, li Oluwa wi; titi lojojumọ li a si nsọ̀rọ odì si orukọ mi.

6. Nitorina awọn enia mi yio mọ̀ orukọ mi li ọjọ na: nitori emi li ẹniti nsọrọ: kiyesi i, emi ni.

7. Ẹsẹ ẹniti o mu ihinrere wá ti dara to lori awọn oke, ti nkede alafia; ti nmu ihìn rere ohun rere wá, ti nkede igbala; ti o wi fun Sioni pe, Ọlọrun rẹ̀ njọba!

8. Awọn alóre rẹ yio gbe ohùn soke; nwọn o jumọ fi ohùn kọrin: nitori nwọn o ri li ojukoju, nigbati Oluwa ba mu Sioni pada.

9. Bú si ayọ̀, ẹ jumọ kọrin, ẹnyin ibi ahoro Jerusalemu: nitori Oluwa ti tù awọn enia rẹ̀ ninu, o ti rà Jerusalemu pada.

10. Oluwa ti fi apá mimọ́ rẹ̀ hàn li oju gbogbo awọn orilẹ-ède; gbogbo opin aiye yio si ri igbala Ọlọrun wa.

11. Ẹ fà sẹhin, é fà sẹhin, é jade kuro lãrin rẹ̀; ẹ má fọwọ kàn ohun aimọ́ kan: ẹ kuro lãrin rẹ̀, ẹ jẹ mimọ́, ẹnyin ti ngbe ohun-èlo Oluwa.

12. Nitori ẹ kì yio yara jade, bẹ̃ni ẹ kì yio fi isare lọ; nitori Oluwa yio ṣãju nyin; Ọlọrun Israeli yio si kó nyin jọ.

Iranṣẹ tí Ń Jìyà

13. Kiyesi i, iranṣẹ mi yio fi oye bá ni lò; a o gbe e ga, a o si gbe e leke, on o si ga gidigidi.

14. Gẹgẹ bi ẹnu rẹ ti yà ọ̀pọlọpọ enia, a bà oju rẹ̀ jẹ ju ti ẹnikẹni lọ, ati irisi rẹ̀ ju ti ọmọ enia lọ.

15. Bẹ̃ni yio buwọ́n ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède; awọn ọba yio pa ẹnu wọn mọ si i, nitori eyi ti a kò ti sọ fun wọn ni nwọn o ri; ati eyi ti nwọn kò ti gbọ́ ni nwọn o rò.