orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36
  37. 37
  38. 38
  39. 39
  40. 40
  41. 41
  42. 42
  43. 43
  44. 44
  45. 45
  46. 46
  47. 47
  48. 48
  49. 49
  50. 50
  51. 51
  52. 52
  53. 53
  54. 54
  55. 55
  56. 56
  57. 57
  58. 58
  59. 59
  60. 60
  61. 61
  62. 62
  63. 63
  64. 64
  65. 65
  66. 66

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 18 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ọlọrun yóo Jẹ Sudani Níyà

1. EGBE ni fun ilẹ ti o ni ojiji apá meji, ti o wà ni ikọja odò Etiopia:

2. Ti o rán awọn ikọ̀ li ọ̀na okun, ani ninu ọkọ̀ koriko odò, li oju odò, wipe, Lọ, ẹnyin onṣẹ ti o yara kánkan, si orilẹ-ède ti a nà ká ti a si tẹju, si enia ti o ni ibẹ̀ru lati igbayi ati titi lọ; orilẹ-ède ti o ni ipá, ti o si tẹ̀ ni mọlẹ, ilẹ ẹniti odò pupọ̀ pinyà!

3. Gbogbo ẹnyin ti ngbe aiye, ati olugbé aiye, ẹ wò, nigbati on gbe ọpagun sori awọn oke giga; ati nigbati on fọn ipè, ẹ gbọ́.

4. Nitori bẹ̃li Oluwa sọ fun mi, emi o simi, emi o si gbèro ninu ibugbé mi, bi oru ọsángangan, ati bi awọsanma ìri, ninu oru ikorè.

5. Nitori ṣaju ikorè, nigbati ìrudi ba kún, ti itanná ba di eso-àjara pipọn on o fi dojé rẹ́ ẹka-titun, yio si mu kuro, yio si ke ẹka lu ilẹ.

6. A o si fi wọn silẹ fun awọn ẹiyẹ oke-nla, ati fun awọn ẹranko aiye: awọn ẹiyẹ yio yá õrùn lori wọn, gbogbo awọn ẹranko aiye yio si potutù lori wọn.

7. Li akoko na ni a o mu ọrẹ wá fun Oluwa awọn ọmọ-ogun lati ọdọ awọn enia ti a nà ka, ti a si tẹju, ati enia ti o ni ibẹ̀ru lati igbayi ati titi lọ; orilẹ-ède ti o ni ipá ti o tẹ̀ ni mọlẹ, ilẹ ẹniti odò pupọ̀ pinyà, si ibi orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, oke giga Sioni.