Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 42:12-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Jẹ ki wọn fi ogo fun Oluwa, ki wọn si wi iyìn rẹ̀ ninu erekùṣu.

13. Oluwa yio jade bi ọkunrin alagbara, yio rú owú soke bi ologun: yio kigbé, nitõtọ, yio ké ramuramu; yio bori awọn ọta rẹ̀.

14. Lailai ni mo ti dakẹ́: mo ti gbe jẹ, mo ti pa ara mi mọra; nisisiyi emi o ké bi obinrin ti nrọbi; emi o parun, emi o si gbé mì lẹ̃kanna.

15. Emi o sọ oke-nla ati òke-kékèké di ofo, emi o si mú gbogbo ewebẹ̀ wọn gbẹ: emi o sọ odò ṣiṣàn di iyangbẹ́ ilẹ, emi o si mú abàta gbẹ.

16. Emi o si mu awọn afọju bá ọ̀na ti nwọn kò mọ̀ wá; emi o tọ́ wọn ninu ipa ti wọn kò ti mọ̀; emi o sọ okùnkun di imọlẹ niwaju wọn, ati ohun wiwọ́ di titọ. Nkan wọnyi li emi o ṣe fun wọn, emi kì yio si kọ̀ wọn silẹ.

17. A o dá awọn ti o gbẹkẹle ere gbigbẹ́ padà, a o doju tì wọn gidigidi, awọn ti nwi fun ere didà pe, Ẹnyin ni ọlọrun wa.

18. Gbọ́, ẹnyin aditi; ki ẹ si wò, ẹnyin afọju ki ẹnyin ki o le ri i.

Ka pipe ipin Isa 42