Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 41:22-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Jẹ ki wọn mú wọn jade wá, ki wọn si fi ohun ti yio ṣe hàn ni: jẹ ki wọn fi ohun iṣãju hàn, bi nwọn ti jẹ, ki awa ki o lè rò wọn, ki a si mọ̀ igbẹ̀hin wọn; tabi ki nwọn sọ ohun wọnni ti mbọ̀ fun wa.

23. Fi ohun ti mbọ̀ lẹhìn eyi hàn, ki awa ki o le mọ̀ pe ọlọrun ni nyin: nitõtọ, ẹ ṣe rere, tabi ẹ ṣe buburu, ki ẹ̀ru le bà wa, ki a le jumọ ri i.

24. Kiyesi i, lati nkan asan ni nyin, iṣẹ nyin si jẹ asan: irira ni ẹniti o yàn nyin.

25. Emi ti gbé ẹnikan dide lati ariwa, on o si wá: lati ilà-õrun ni yio ti ké pe orukọ mi: yio si wá sori awọn ọmọ-alade bi sori àmọ, ati bi alamọ̀ ti itẹ̀ erupẹ.

26. Tani o ti fi hàn lati ipilẹ̀ṣẹ, ki awa ki o le mọ̀? ati nigba iṣãju, ki a le wi pe, Olododo ni on? nitõtọ, kò si ẹnikan ti o fi hàn, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o sọ ọ, nitõtọ, kò si ẹnikan ti o gbọ́ ọ̀rọ nyin.

27. Ẹni-ikini o wi fun Sioni pe, Wò o, on na nĩ: emi o fi ẹnikan ti o mú ihinrere wá fun Jerusalemu.

28. Nitori mo wò, kò si si ẹnikan; ani ninu wọn, kò si si olugbimọ̀ kan, nigbati mo bere lọwọ wọn, kò si ẹniti o le dahùn ọ̀rọ kan.

29. Kiyesi i, asan ni gbogbo wọn; asan ni iṣẹ wọn; ẹfũfu ati rudurudu ni ere didà wọn.

Ka pipe ipin Isa 41