Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 37:9-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. O si gbọ́ a nwi niti Tirhaka ọba Etiopia, pe, O mbọ̀ wá ba iwọ jagun. Nigbati o si gbọ́, o rán awọn ikọ̀ lọ sọdọ Hesekiah, wipe,

10. Bayi ni ki ẹ wi fun Hesekiah ọba Juda, pe, Má jẹ ki Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ gbẹkẹle, ki o tàn ọ jẹ, wipe, A kì yio fi Jerusalemu le ọba Assiria lọwọ.

11. Kiyesi i, iwọ ti gbọ́ ohun ti awọn ọba Assiria ti ṣe si ilẹ gbogbo bi nwọn ti pa wọn run patapata: a o si gbà iwọ bi?

12. Oriṣa awọn orilẹ-ède ha gbà awọn ti awọn baba mi ti parun bi? bi Gosani, ati Harani ati Resefu, ati awọn ọmọ Edeni ti nwọn ti wà ni Telassari?

13. Nibo ni ọba Hamati wà, ati ọba Arfadi, ati ọba ilu Sefarfaimu, Hena, ati Ifa?

14. Hesekiah si gbà iwe na lọwọ awọn ikọ̀, o si kà a: Hesekiah si gòke lọ si ile Oluwa, o si tẹ́ ẹ siwaju Oluwa.

15. Hesekiah si gbadura si Oluwa, wipe,

16. Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, ti ngbe ãrin awọn kerubu, iwọ li Ọlọrun, ani iwọ nikan, ninu gbogbo ijọba aiye: iwọ li o dá ọrun on aiye.

17. Dẹti rẹ silẹ, Oluwa, ki o si gbọ́; ṣi oju rẹ, Oluwa, ki o si wò: si gbọ́ gbogbo ọ̀rọ Senakeribu, ti o ranṣẹ lati kẹgàn Ọlọrun alãyè.

18. Lõtọ ni, Oluwa, awọn ọba Assiria ti sọ gbogbo orilẹ-ède di ahoro, ati ilẹ wọn,

19. Nwọn si ti sọ awọn òriṣa wọn sinu iná: nitori ọlọrun ki nwọn iṣe, ṣugbọn iṣẹ ọwọ́ enia ni, igi ati òkuta: nitorina ni nwọn ṣe pa wọn run.

20. Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun wa, gbà wa lọwọ rẹ̀, ki gbogbo ijọba aiye le mọ̀ pe iwọ ni Oluwa, ani iwọ nikanṣoṣo.

21. Nigbana ni Isaiah ọmọ Amosi ranṣẹ si Hesekiah, wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niwọ̀n bi iwọ ti gbadura si mi niti Sennakeribu ọba Assiria:

22. Eyi ni ọ̀rọ ti Oluwa ti sọ niti rẹ̀: Wundia, ọmọbinrin Sioni, ti kẹ́gàn rẹ, o si ti fi ọ rẹrin ẹlẹyà; ọmọbinrin Jerusalemu ti mì ori rẹ̀ si ọ.

Ka pipe ipin Isa 37