Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 37:28-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Ṣugbọn mo mọ̀ ibugbe rẹ, ijadelọ rẹ, ati iwọle rẹ, ati irúnu rẹ si mi.

29. Nitori irúnu rẹ si mi, ati igberaga rẹ, ti goke wá si eti mi, nitorina ni emi o ṣe fi ìwọ mi kọ́ ọ ni imú, ati ijanu mi si ète rẹ, emi o si mu ọ pada li ọ̀na ti o ba wá.

30. Eyi ni o si jẹ àmi fun ọ, Ẹ jẹ ilalẹ̀hu li ọdun yi; ati li ọdun keji eyiti o sọ jade ninu ọkanna: ati li ọdun kẹta ẹ fọnrugbìn, ki ẹ si kore, ki ẹ si gbìn ọgba àjara, ki ẹ si jẹ eso wọn.

31. Ati iyokù ti o sala ninu ile Juda yio tun fi gbòngbo mulẹ nisalẹ, yio si so eso loke:

32. Nitori lati Jerusalemu ni iyokù yio jade lọ, ati awọn ti o sala lati oke Sioni wá: itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.

33. Nitorina bayi ni Oluwa wi niti ọba Assiria, on kì yio wá si ilu yi, bẹ̃ni kì yio ta ọfà kan sibẹ, kì yio si mu asà wá siwaju rẹ̀, bẹ̃ni kì yio wà odi tì i.

34. Li ọ̀na ti o ba wá, li ọkanna ni yio bá padà, kò si ni wá si ilu yi, li Oluwa wi.

35. Nitori emi o dãbo bò ilu yi lati gbà a nitoriti emi tikala mi, ati nitoriti Dafidi iranṣẹ mi.

36. Angeli Oluwa si jade lọ, o si pa ọkẹ́ mẹsan o le ẹgbẹ̃dọgbọn ni budo awọn ara Assiria; nigbati nwọn si dide lowurọ kùtukutu, kiyesi i, gbogbo wọn jẹ okú.

37. Bẹ̃ni Sennakeribu ọba Assiria mu ọ̀na rẹ̀ pọ̀n, o si lọ, o si padà, o si ngbe Ninefe.

38. O si di igbati o ṣe, bi o ti ntẹriba ni ile Nisroki oriṣa rẹ̀, ni Adrammeleki ati Ṣaresari awọn ọmọ rẹ̀ fi idà pa a; nwọn si salà si ilẹ Armenia: Esarhaddoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin Isa 37