Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 36:12-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ṣugbọn Rabṣake wipe, Oluwa mi ha rán mi si oluwa rẹ lati sọ ọ̀rọ wọnyi? kò ha ran mi sọdọ awọn ọkunrin ti o joko lori odi, ki nwọn ki o le ma jẹ igbẹ́ ara wọn, ki nwọn si ma mu ìtọ ara wọn pẹlu nyin?

13. Nigbana ni Rabṣake duro, o si fi ohùn rara kigbe li ède awọn Ju, o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ọba nla, ọba Assiria.

14. Bayi ni ọba na wi, pe, Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah tàn nyin jẹ: nitori on kì o lè gbà nyin.

15. Ẹ máṣe jẹ ki Hesekiah ki o mu nyin gbẹkẹle Oluwa, wipe, Ni gbigbà Oluwa yio gbà wa, a ki o fi ilu yi le ọba Assiria lọwọ.

16. Ẹ máṣe fetisi ti Hesekiah: nitori bayi li ọba Assiria wi pe, Ẹ fi ẹ̀bun bá mi rẹ́, ki ẹ si jade tọ̀ mi wá: ki olukuluku nyin ma jẹ ninu àjara rẹ̀, ati olukuluku nyin ninu igi ọ̀pọtọ́ rẹ̀, ki olukuluku nyin si ma mu omi ninu àmu on tikalarẹ̀;

17. Titi emi o fi wá lati mu nyin lọ si ilẹ kan bi ilẹ ẹnyin tikala nyin, ilẹ ọkà ati ọti-waini, ilẹ onjẹ ati ọ̀gba àjara.

18. Ẹ ṣọra ki Hesekiah ki o má pa nyin niyè dà wipe, Oluwa yio gbà wa, ọkan ninu òriṣa awọn orilẹ-ède ha gba ilẹ rẹ̀ lọwọ ọba Assiria ri bi?

19. Nibo li awọn òriṣa Hamati on Arfardi gbe wà? Nibo li awọn òriṣa Sefarfaimu wà? nwọn ha si ti gbà Samaria li ọwọ́ mi bi?

20. Tani ninu gbogbo oriṣa ilẹ wọnyi, ti o ti gbà ilẹ wọn kuro li ọwọ́ mi, ti Oluwa yio fi gbà Jerusalemu kuro li ọwọ́ mi?

Ka pipe ipin Isa 36