Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 33:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EGBÉ ni fun iwọ abanijẹ, ti a kò si bà ọ jẹ: ti o nhùwa arekereke, ti a kò si hùwa arekereke si ọ! nigbati iwọ o dẹkun ati banijẹ, a o bà ọ jẹ; ati nigbati iwọ bá fi opin si ihùwa arekereke, nwọn o hùwa arekereke si ọ.

2. Oluwa, ṣãnu fun wa; awa ti duro dè ọ: iwọ mã ṣe apá wọn li òròwúrọ̀ ani igbala wa nigba ipọnju.

3. Li ariwo irọ́kẹ̀kẹ li awọn enia sá, ni gbigbe ara rẹ soke li a fọ́n awọn orilẹ-ède ká.

4. A o si ṣà ikogun nyin jọ bi ikojọ awọn ẹlẹngà: bi isure siwa, isure sẹhìn awọn eṣú, li on o sure si wọn.

5. Gbigbega li Oluwa; nitori on ngbe ibi giga: on ti fi idajọ ati ododo kún Sioni.

6. On o si jẹ iduroṣinṣin akoko rẹ̀, iṣura igbala, ọgbọ́n ati ìmọ; ìbẹru Oluwa ni yio jẹ iṣura rẹ̀.

7. Kiyesi i, awọn akọni kigbe lode, awọn ikọ̀ alafia sọkún kikorò.

8. Ọ̀na opopo nla wọnni ṣófo, èro dá, on ti bà majẹmu jẹ, o ti kẹgàn ilu wọnni, kò kà ẹnikan si.

9. Ilẹ ngbawẹ̀ o si njoro, oju ntì Lebanoni o si rọ: Ṣaroni dabi aginju; ati Baṣani ati Karmeli gbọ̀n eso wọn danù.

10. Oluwa wipe, nisisiyi li emi o dide, nisisiyi li emi o gbe ara mi soke.

11. Ẹ o loyun iyangbò, ẹ o si bi pòropóro; ẽmi nyin, bi iná, yio jẹ nyin run.

12. Awọn enia yio si dabi sisun ẽru, bi ẹgún ti a ké ni nwọn o jo ninu iná.

13. Ẹ gbọ́, ẹnyin ti o jìna rére, eyi ti mo ti ṣe; ati ẹnyin ti o sunmọ tosí, ẹ jẹwọ agbara mi.

14. Ẹ̀ru bà awọn ẹlẹṣẹ̀ ni Sioni; ibẹru-bojo ti mu awọn agabàgebè. Tani ninu wa ti o le gbe inu ajonirun iná? tani ninu wa ti yio le gbe inu iná ainipẹkun?

15. Ẹniti nrìn li ododo, ti o si nsọ̀rọ titọ́; ẹniti o gàn ère ininilara, ti o gbọ̀n ọwọ́ rẹ̀ kuro ni gbigbà abẹtẹlẹ, ti o di eti rẹ ni gbigbọ́ ti ẹ̀jẹ, ti o si di oju rẹ̀ ni riri ibi.

Ka pipe ipin Isa 33