Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isa 25:5-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Iwọ o mu ariwo awọn alejo rọlẹ, gẹgẹ bi oru nibi gbigbẹ; ani oru pẹlu ojiji awọsanma: a o si rẹ̀ orin-ayọ̀ awọn ti o ni ibẹ̀ru silẹ.

6. Ati ni oke-nla yi li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sè asè ohun abọ́pa fun gbogbo orilẹ-ède, asè ọti-waini lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ, ti ohun abọpa ti o kún fun ọra, ti ọti-waini ti o tòro lori gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ.

7. Li oke-nla yi on o si pa iboju ti o bò gbogbo enia loju run, ati iboju ti a nà bò gbogbo orilẹ-ède.

8. On o gbe iku mì lailai; Oluwa Jehofah yio nù omije nù kuro li oju gbogbo enia; yio si mu ẹ̀gan enia rẹ̀ kuro ni gbogbo aiye: nitori Oluwa ti wi i.

9. A o si sọ li ọjọ na pe, Wò o, Ọlọrun wa li eyi; awa ti duro de e, on o si gbà wa là: Oluwa li eyi: awa ti duro de e, awa o ma yọ̀, inu wa o si ma dùn ninu igbala rẹ̀.

10. Nitori li oke-nla yi ni ọwọ́ Oluwa yio simi, yio si tẹ Moabu labẹ rẹ̀, ani gẹgẹ bi ãti tẹ̀ koriko mọlẹ fun ãtan.

11. Yio si nà ọwọ́ rẹ̀ jade li ãrin wọn, gẹgẹ bi òmùwẹ̀ iti nà ọwọ́ rẹ̀ jade lati wẹ̀: on o si rẹ̀ igberaga wọn silẹ pọ̀ pẹlu ikogun ọwọ́ wọn.

12. Odi alagbara, odi giga, odi rẹ li on o wó lulẹ, yio rẹ̀ ẹ silẹ, yio mu u wá ilẹ, ani sinu ekuru.

Ka pipe ipin Isa 25