Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 7:14-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Bi awọn enia mi ti a npè orukọ mi mọ́, ba rẹ̀ ara wọn silẹ, ti nwọn ba si gbadura, ti nwọn ba si wá oju mi, ti nwọn ba si yipada kuro ninu ọ̀na buburu wọn; nigbana ni emi o gbọ́ lati ọrun wá, emi o si dari ẹ̀ṣẹ wọn jì, emi o si wò ilẹ wọn sàn.

15. Nisisiyi oju mi yio ṣí, eti mi yio si tẹ́ si adura ibi yi.

16. Njẹ nisisiyi emi ti yàn, emi si ti yà ile yi si mimọ́, ki orukọ mi ki o le ma wà nibẹ lailai: ati oju mi ati ọkàn mi yio ma wà nibẹ nigbagbogbo.

17. Ati iwọ, bi iwọ o ba rìn niwaju mi bi Dafidi, baba rẹ ti rìn, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo ti pa li aṣẹ fun ọ, bi iwọ o ba si ṣe akiyesi aṣẹ mi ati idajọ mi;

18. Nigbana ni emi o fi idi itẹ ijọba rẹ múlẹ̀, gẹgẹ bi emi ti ba Dafidi, baba rẹ dá majẹmu, wipe, a kì yio fẹ ẹnikan kù fun ọ ti yio ma ṣe akoso ni Israeli.

19. Ṣugbọn bi ẹnyin ba yipada, ti ẹ ba si kọ̀ aṣẹ mi ati ofin mi silẹ, ti emi ti gbé kalẹ niwaju nyin, ti ẹnyin ba si sin ọlọrun miran, ti ẹ si bọ wọn;

20. Nigbana ni emi o fà wọn tu ti-gbongbo-ti-gbongbo kuro ni ilẹ ti emi ti fi fun wọn; ati ile yi, ti emi ti yà si mimọ́ fun orukọ mi, li emi o ta nù kuro niwaju mi, emi o si sọ ọ di owe, ati ọ̀rọ-ẹgan larin gbogbo orilẹ-ède.

Ka pipe ipin 2. Kro 7