Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 33:7-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. O si gbé ere gbigbẹ kalẹ, ere ti o ti yá sinu ile Ọlọrun, niti eyiti Ọlọrun ti sọ fun Dafidi ati Solomoni, ọmọ rẹ̀, pe, Ninu ile yi, ati ni Jerusalemu ti emi ti yàn ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli, li emi o fi orukọ mi si lailai:

8. Bẹ̃li emi kì yio ṣi ẹsẹ Israeli mọ kuro ni ilẹ na ti emi ti yàn fun awọn baba nyin; kiki bi nwọn ba ṣe akiyesi lati ṣe gbogbo eyiti emi ti pa li aṣẹ fun wọn, gẹgẹ bi gbogbo ofin ati aṣẹ ati ilana lati ọwọ Mose wá.

9. Bẹ̃ni Manasse mu ki Judah ati awọn ti ngbe Jerusalemu ki o yapa, ati lati ṣe buburu jù awọn orilẹ-ède lọ, awọn ẹniti Oluwa ti parun niwaju awọn ọmọ Israeli.

10. Oluwa si ba Manasse wi ati awọn enia rẹ̀; ṣugbọn nwọn kò kiyesi i.

11. Nitorina li Oluwa mu awọn balogun ogun Assiria wá ba wọn, ti nwọn fi ìwọ mu Manasse, nwọn si de e li ẹ̀wọn, nwọn mu u lọ si Babeli.

12. Nigbati o si wà ninu wahala, o bẹ̀ Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ gidigidi niwaju Ọlọrun awọn baba rẹ̀,

13. O si gbadura si i: Ọlọrun si gbọ́ ẹ̀bẹ rẹ̀, o si tun mu u pada wá si Jerusalemu sinu ijọba rẹ̀. Nigbana ni Manasse mọ̀ pe: Oluwa, On li Ọlọrun.

14. Njẹ lẹhin eyi, o mọ odi kan lẹhin ilu Dafidi, niha ìwọ-õrun Gihoni, li àfonifoji, ani li atiwọ ẹnu-bode ẹja, o si yi Ofeli ka, o si mọ ọ ga soke gidigidi, o si fi balogun sinu gbogbo ilú olodi Juda wọnni.

15. O si kó awọn àjeji ọlọrun ati ere kuro ni ile Oluwa, ati gbogbo pẹpẹ ti o ti tẹ́ lori òke ile Oluwa ati ni Jerusalemu, o si kó wọn danu kuro ni ilu.

Ka pipe ipin 2. Kro 33