Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 32:27-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Hesekiah si li ọrọ̀ li ọ̀pọlọpọ ati ọlá: o si ṣe ibi-iṣura fun ara rẹ̀ fun fadakà, ati fun wura, ati fun okuta iyebiye, ati fun turari ati fun apata, ati fun oniruru ohun-elo iyebiye.

28. Ile-iṣura pẹlu fun ibisi ọkà, ati ọti-waini; ati ororo; ati ile fun gbogbo oniruru ẹran, ati ọgbà fun agbo-ẹran.

29. Pẹlupẹlu o ṣe ilu fun ara rẹ̀, ati agbo agutan ati agbo malu li ọ̀pọlọpọ: nitoriti Ọlọrun fun u li ọrọ̀ li ọ̀pọlọpọ.

30. Hesekiah kanna yi li o dí ipa-omi ti o wà li òke Gihoni pẹlu, o si mu u wá isalẹ tara si iha iwọ-õrun ilu Dafidi. Hesekiah si ṣe rere ni gbogbo iṣẹ rẹ̀.

31. Ṣugbọn niti awọn ikọ̀ awọn ọmọ-alade Babeli, ti nwọn ranṣẹ si i, lati bère ohun-iyanu ti a ṣe ni ilẹ na, Ọlọrun fi i silẹ lati dán a wò, ki o le mọ̀ ohun gbogbo ti o wà li ọkàn rẹ̀.

32. Ati iyokù iṣe Hesekiah ati iṣẹ rere rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe iran Isaiah woli, ọmọ Amosi, ani ninu iwe awọn ọba Juda ati Israeli.

33. Hesekiah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sin i ninu iboji awọn ọmọ Dafidi: ati gbogbo Juda ati awọn ti ngbe Jerusalemu ṣe ẹyẹ fun u ni iku rẹ̀. Manasse ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Kro 32