Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 31:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ nigbati gbogbo eyi pari, gbogbo Israeli ti a ri nibẹ jade lọ si ilu Juda wọnni, nwọn si fọ́ awọn ere tũtu, nwọn si bẹ́ igbo òriṣa lulẹ, nwọn si bì ibi giga wọnni ati awọn pẹpẹ ṣubu, ninu gbogbo Juda ati Benjamini, ni Efraimu pẹlu ati Manasse, titi nwọn fi pa gbogbo wọn run patapata. Nigbana ni gbogbo awọn ọmọ Israeli yipada, olukuluku si ilẹ-ini rẹ̀ si ilu wọn.

2. Hesekiah si yàn ipa awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi nipa ipa wọn, olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin rẹ̀, awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi fun ẹbọ sisun, ati fun ẹbọ-alafia lati ṣiṣẹ, ati lati dupẹ, ati lati ma yìn li ẹnu-ọ̀na ibudo Oluwa.

3. Ọba si fi ipin lati inu ini rẹ̀ sapakan fun ẹbọ sisun, fun ẹbọ sisun orowurọ ati alalẹ, ati ẹbọ sisun ọjọjọ isimi, ati fun oṣù titun, ati fun ajọ ti a yàn, bi a ti kọ ọ ninu ofin Oluwa.

4. Pẹlupẹlu o paṣẹ fun awọn enia ti ngbe Jerusalemu lati fi ipin kan fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ki o le di ofin Oluwa mu ṣinṣin.

5. Bi aṣẹ na ti de ode, awọn ọmọ Israeli mu ọ̀pọlọpọ akọso ọkà ati ọti-waini ati ororo, ati oyin wá, ati ninu gbogbo ibisi oko; ati idamẹwa ohun gbogbo ni nwọn mu wá li ọ̀pọlọpọ.

6. Ati awọn ọmọ Israeli ati Juda, ti ngbe inu ilu Juda wọnni, awọn pẹlu mu idamẹwa malu ati agutan wá ati idamẹwa gbogbo ohun mimọ́ ti a yà si mimọ́ si Oluwa Ọlọrun wọn, nwọn si kó wọn jọ li òkiti òkiti.

7. Li oṣù kẹta, nwọn bẹ̀rẹ si ifi ipilẹ awọn òkiti lelẹ, nwọn si pari rẹ̀ li oṣù keje.

8. Nigbati Hesekiah ati awọn ijoye de, ti nwọn si ri òkiti wọnni, nwọn fi ibukún fun Oluwa, ati Israeli enia rẹ̀.

9. Hesekiah si bère lọdọ awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi niti òkiti wọnni.

10. Asariah, olori alufa ti ile Sadoku, si da a lohùn o si wipe, Lati igba ti awọn enia bẹ̀rẹ si imu ọrẹ wá sinu ile Oluwa, awa ní to lati jẹ, a si kù pupọ silẹ: Oluwa sa ti bukún awọn enia rẹ̀; eyiti o kù ni iṣura nla yi.

11. Nigbana ni Hesekiah paṣẹ lati pèse iyàrá-iṣura ni ile Ọlọrun; nwọn si pèse wọn.

12. Nwọn si mu awọn ọrẹ ati idamẹwa ati ohun ti a yà si mimọ́ wọ̀ ile wá nitõtọ: lori eyiti Kononiah, ọmọ Lefi, nṣe olori, Ṣimei arakunrin rẹ̀ si ni igbakeji.

13. Ati Jehieli, ati Asasiah, ati Nahati, ati Asaheli, ati Jerimoti, ati Josabadi, ati Elieli, ati Ismakiah, ati Mahati, ati Benaiah, ni awọn alabojuto labẹ ọwọ Kononiah ati Ṣimei arakunrin rẹ̀, nipa aṣẹ Hesekiah ọba, ati Asariah, olori ile Ọlọrun.

14. Ati Kore, ọmọ Imna, ọmọ Lefi, adèna iha ila-õrun, li o wà lori awọn ọrẹ atinuwa Ọlọrun, lati pin ẹbọ ọrẹ Oluwa, ati ohun mimọ́ julọ.

Ka pipe ipin 2. Kro 31