Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 30:14-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Nwọn si dide, nwọn si kó gbogbo pẹpẹ ti o wà ni Jerusalemu lọ, ati gbogbo pẹpẹ turari ni nwọn kó lọ, nwọn si dà wọn si odò Kidroni.

15. Nigbana ni nwọn pa ẹran irekọja na li ọjọ kẹrinla oṣù keji: oju si tì awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, nwọn si yà ara wọn si mimọ́, nwọn si mu ẹbọ sisun wá sinu ile Oluwa.

16. Nwọn si duro ni ipò wọn, bi ètò wọn gẹgẹ bi ofin Mose, enia Ọlọrun: awọn alufa wọ́n ẹ̀jẹ na, ti nwọn gbà lọwọ awọn ọmọ Lefi.

17. Nitori ọ̀pọlọpọ li o wà ninu ijọ enia na ti kò yà ara wọn si mimọ́: nitorina ni awọn ọmọ Lefi ṣe ntọju ati pa ẹran irekọja fun olukuluku ẹniti o ṣe alaimọ́, lati yà a si mimọ́ si Oluwa.

18. Ọ̀pọlọpọ enia, ani ọ̀pọlọpọ ninu Efraimu ati Manasse, Issakari, ati Sebuluni kò sa wẹ̀ ara wọn mọ́ sibẹ nwọn jẹ irekọja na, kì iṣe gẹgẹ bi a ti kọ ọ. Ṣugbọn Hesekiah bẹ̀bẹ fun wọn, wipe, Oluwa, ẹni-rere, dariji olukuluku,

19. Ti o mura ọkàn rẹ̀ lati wá Ọlọrun, Oluwa Ọlọrun awọn baba rẹ̀, ṣugbọn ti kì iṣe nipa ìwẹnumọ́ mimọ́.

20. Oluwa si gbọ́ ti Hesekiah, o si mu awọn enia na lara dá.

21. Awọn ọmọ Israeli ti a ri ni Jerusalemu fi ayọ̀ nla pa ajọ àkara alaiwu mọ́ li ọjọ meje: awọn ọmọ Lefi, ati awọn alufa yìn Oluwa lojojumọ, nwọn nfi ohun-elo olohùn goro kọrin si Oluwa.

22. Hesekiah sọ̀rọ itunu fun gbogbo awọn ọmọ Lefi, ti o loye ni ìmọ rere Oluwa: ijọ meje ni nwọn fi jẹ àse na, nwọn nru ẹbọ alafia, nwọn si nfi ohùn rara dupẹ fun Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn.

23. Gbogbo ijọ na si gbìmọ lati pa ọjọ meje miran mọ́: nwọn si fi ayọ̀ pa ọjọ meje miran mọ́.

24. Nitori Hesekiah, ọba Juda, ta ijọ enia na li ọrẹ, ẹgbẹrun akọ-malu, ati ẹ̃dẹgbãrun àgutan: ọ̀pọlọpọ ninu awọn alufa si yà ara wọn si mimọ́.

25. Gbogbo ijọ-enia Juda pẹlu awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo ijọ-enia ti o ti inu Israeli jade wá, ati awọn àlejo ti o ti ilẹ Israeli jade wá, ati awọn ti ngbe Juda yọ̀.

26. Bẹ̃li ayọ̀ nla si wà ni Jerusalemu: nitori lati ọjọ Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israeli, iru eyi kò sí ni Jerusalemu.

27. Nigbana li awọn alufa, awọn ọmọ Lefi dide, nwọn si sure fun awọn enia na: a si gbọ́ ohùn wọn, adura wọn si gòke lọ si ibugbe mimọ́ rẹ̀, ani si ọrun.

Ka pipe ipin 2. Kro 30