Nigbana ni nwọn pa ẹran irekọja na li ọjọ kẹrinla oṣù keji: oju si tì awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, nwọn si yà ara wọn si mimọ́, nwọn si mu ẹbọ sisun wá sinu ile Oluwa.