Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 20:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe, lẹhin eyi li awọn ọmọ Moabu, ati awọn ọmọ Ammoni, ati ninu awọn ọmọ Edomu pẹlu wọn, gbé ogun tọ Jehoṣafati wá.

2. Nigbana li awọn kan wá, nwọn si wi fun Jehoṣafati pe, Ọ̀pọlọpọ enia mbo wá ba ọ lati apakeji okun lati Siria, si kiyesi i, nwọn wà ni Hasason-Tamari ti iṣe Engedi.

3. Jehoṣafati si bẹ̀ru, o si fi ara rẹ̀ si ati wá Oluwa, o si kede àwẹ ja gbogbo Juda.

4. Juda si kó ara wọn jọ, lati wá iranlọwọ lọwọ Oluwa: pẹlupẹlu nwọn wá lati inu gbogbo ilu Juda lati wá Oluwa,

5. Jehoṣafati si duro ninu apejọ enia Juda ati Jerusalemu, ni ile Oluwa, niwaju àgbala titun.

6. O si wipe, Oluwa, Ọlọrun awọn baba wa, iwọ kọ́ ha ni Ọlọrun li ọrun? Iwọ kọ́ ha nṣakoso lori gbogbo ijọba awọn orilẹ-ède? lọwọ rẹ ki agbara ati ipá ha wà, ti ẹnikan kò si, ti o le kò ọ loju?

7. Iwọ ha kọ́ Ọlọrun wa, ti o ti le awọn ara ilẹ yi jade niwaju Israeli enia rẹ, ti o si fi fun iru-ọmọ Abrahamu, ọrẹ rẹ lailai?

8. Nwọn si ngbe inu rẹ̀, nwọn si kọ́ ibi-mimọ́ fun ọ ninu rẹ̀ fun orukọ rẹ, pe,

9. Bi ibi ba de si wa, bi idà, ijiya tabi àjakalẹ-àrun, tabi ìyan, bi awa ba duro niwaju ile yi, ati niwaju rẹ, (nitori orukọ rẹ wà ni ile yi): bi a ba ke pè ọ ninu wàhala wa, nigbana ni iwọ o gbọ́, iwọ o si ṣe iranlọwọ.

10. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, awọn ọmọ Ammoni ati Moabu, ati awọn ara òke Seiri, ti iwọ kò jẹ ki Israeli gbogun si nigbati nwọn jade ti ilẹ Egipti wá, ṣugbọn nwọn yipada kuro lọdọ wọn, nwọn kò si run wọn;

11. Si kiyesi i, bi nwọn ti san a pada fun wa; lati wá le wa jade kuro ninu ini rẹ, ti iwọ ti fi fun wa lati ni.

12. Ọlọrun wa! Iwọ kì o ha da wọn lẹjọ? nitori awa kò li agbara niwaju ọ̀pọlọpọ nla yi, ti mbọ̀ wá ba wa; awa kò si mọ̀ eyi ti awa o ṣe: ṣugbọn oju wa mbẹ lara rẹ.

13. Gbogbo Juda si duro niwaju Oluwa, pẹlu awọn ọmọ wẹrẹ wọn, obinrin wọn, ati ọmọ wọn.

14. Ṣugbọn lori Jahasieli, ọmọ Sekariah, ọmọ Benaiah, ọmọ Jeieli, ọmọ Mattaniah, ọmọ Lefi kan ninu awọn ọmọ Asafu, ni ẹmi Oluwa wá li ãrin apejọ enia na.

15. O si wipe, Ẹ tẹti silẹ, gbogbo Judah, ati ẹnyin olugbe Jerusalemu, ati iwọ Jehoṣafati ọba; Bayi li Oluwa wi fun nyin, Ẹ máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe fòya nitori ọ̀pọlọpọ enia yi; nitori ogun na kì iṣe ti nyin bikòṣe ti Ọlọrun.

Ka pipe ipin 2. Kro 20