Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 13:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Abijah si fi awọn alagbara akọni ologun dì ogun na, ani ogún ọkẹ́ enia ti a yàn, Jeroboamu pẹlu si fi ogoji ọkẹ enia ti a yàn, awọn alagbara akọni enia tẹ́ ogun si i.

4. Abijah si duro lori oke Semaraimu, ti o wà li òke Efraimu, o si wipe, Ẹ gbọ́ temi, Jeroboamu ati gbogbo Israeli!

5. Kò ha tọ́ ki ẹnyin ki o mọ̀ pe: Oluwa Ọlọrun Israeli fi ijọba lori Israeli fun Dafidi lailai, ani fun u, ati fun awọn ọmọ rẹ̀ nipa majẹmu iyọ̀?

6. Jeroboamu, ọmọ Nebati, iranṣẹ Solomoni, ọmọ Dafidi dide, o si ṣọ̀tẹ si oluwa rẹ̀.

7. Awọn enia lasan si ko ara wọn jọ si ọdọ rẹ̀, awọn ọmọ ẹni buburu, nwọn si mu ara wọn le si Rehoboamu, ọmọ Solomoni, nigbati Rehoboamu wà li ọdọmọde ti inu rẹ̀ si rọ̀, ti kò si le kò wọn loju.

8. Ati nisisiyi ẹnyin rò lati kò ijọba Oluwa loju li ọwọ ọmọ Dafidi; ọ̀pọlọpọ si li ẹnyin, ati pẹlu nyin awọn ẹgbọrọmalu wura ti Jeroboamu ṣe li ọlọrun fun nyin.

9. Ẹnyin kò ha ti lé awọn alufa Oluwa jade, awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi, ẹnyin si ti ṣe awọn alufa fun ara nyin, gẹgẹ bi iṣe awọn orilẹ-ède ilẹ miran? bẹ̃ni ẹnikẹni ti o ba wá, ti ọwọ rẹ kún pẹlu ọdọ-akọ-malu ati àgbo meje, on na le ma ṣe alufa awọn ti kì iṣe ọlọrun.

10. Ṣugbọn bi o ṣe ti wa ni, Oluwa li Ọlọrun wa, awa kò si kọ̀ ọ silẹ ati awọn alufa, ti nṣe iranṣẹ fun Oluwa, ani awọn ọmọ Aaroni ati awọn ọmọ Lefi ninu iṣẹ wọn.

Ka pipe ipin 2. Kro 13