Ẹnyin kò ha ti lé awọn alufa Oluwa jade, awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi, ẹnyin si ti ṣe awọn alufa fun ara nyin, gẹgẹ bi iṣe awọn orilẹ-ède ilẹ miran? bẹ̃ni ẹnikẹni ti o ba wá, ti ọwọ rẹ kún pẹlu ọdọ-akọ-malu ati àgbo meje, on na le ma ṣe alufa awọn ti kì iṣe ọlọrun.