Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 9:18-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Saulu si sunmọ Samueli li ẹnu-ọna ilu, o si wipe, Sọ fun mi, emi bẹ ọ, nibo ni ile arina gbe wà?

19. Samueli da Saulu lohùn o si wipe, emi ni arina na: goke lọ siwaju mi ni ibi giga, ẹ o si ba mi jẹun loni, li owurọ̀ emi o si jẹ ki o lọ, gbogbo eyi ti o wà li ọkàn rẹ li emi o sọ fun ọ.

20. Niti awọn kẹtẹkẹtẹ rẹ ti o ti nù lati iwọn ijọ mẹta wá, má fi ọkàn si wọn; nitoriti nwọn ti ri wọn. Si tani gbogbo ifẹ, Israeli wà? Ki iṣe si ọ ati si ile baba rẹ?

21. Saulu si dahùn o si wipe, Ara Benjamini ki emi iṣe? kekere ninu ẹya Israeli? idile mi kò si rẹhìn ninu gbogbo ẹya Benjamini? ẽsi ti ṣe ti iwọ sọrọ yi si mi?

22. Samueli si mu Saulu ati iranṣẹ rẹ̀, o si mu wọn wọ inu gbàngàn, o si fun wọn ni ijoko lãrin awọn agbagba ninu awọn ti a pè, nwọn si to ọgbọ̀n enia.

23. Samueli si wi fun alase pe, Mu ipin ti mo ti fi fun ọ wá, eyi ti mo ti sọ fun ọ pe, Ki o fi i pamọ sọdọ rẹ.

24. Alase na si gbe ejika na, ati eyi ti o wà lori rẹ̀, o si gbe e kalẹ niwaju Saulu. Samueli si wipe, Wo eyi ti a fi silẹ! fà a sọdọ rẹ, ki o si ma jẹ: nitoripe titi di isisiyi li ati pa a mọ fun ọ lati igbati mo ti wipe, emi ti pe awọn enia na. Bẹ̃ni Saulu si ba Samueli jẹun li ọjọ na.

25. Nigbati nwọn sọkalẹ lati ibi giga nì wá si ilu, Samueli si ba Saulu sọrọ lori orule.

26. Nwọn si dide ni kutukutu: o si ṣe, li afẹmọjumọ, Samueli si pe Saulu sori orule, wipe, Dide, emi o si ran ọ lọ. Saulu si dide, awọn mejeji sì jade, on ati Samueli, si gbangba.

27. Bi nwọn si ti nsọkalẹ lọ si ipẹkun ilu na, Samueli wi fun Saulu pe, Wi fun iranṣẹ ki o kọja si iwaju wa, (o si kọja) ṣugbọn ki iwọ ki o duro diẹ, ki emi ki o le fi ọ̀rọ Ọlọrun hàn ọ́.

Ka pipe ipin 1. Sam 9