Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 6:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. APOTI Oluwa wà ni ilẹ awọn Filistini li oṣù meje.

2. Awọn Filistini si pe awọn alufa ati awọn alasọtẹlẹ, wipe, Awa o ti ṣe apoti Oluwa si? sọ fun wa ohun ti awa o fi rán a lọ si ipò rẹ̀.

3. Nwọn si wipe, Bi ẹnyin ba rán apoti Ọlọrun Israeli lọ, máṣe rán a lọ lofo; ṣugbọn bi o ti wu ki o ri, ẹ ṣe irubọ ẹbi fun u; a o si mu nyin lara da, ẹnyin o si mọ̀ ohun ti o ṣe ti ọwọ́ rẹ̀ kò fi kuro li ara nyin.

4. Nwọn wipe, Kini irubọ na ti a o fi fun u? Nwọn si dahun pe, Iyọdi wura marun, ati ẹ̀liri wura marun, gẹgẹ bi iye ijoye Filistini: nitoripe ajakalẹ arùn kanna li o wà li ara gbogbo nyin, ati awọn ijoye nyin.

5. Nitorina ẹnyin o ya ere iyọdi nyin, ati ere ẹ̀liri nyin ti o bà ilẹ na jẹ; ẹnyin o si fi ogo fun Ọlọrun Israeli: bọya yio mu ọwọ́ rẹ̀ fẹrẹ lara nyin, ati lara awọn ọlọrun nyin, ati kuro lori ilẹ nyin,

6. Njẹ ẽtiṣe ti ẹnyin fi se aiya nyin le, bi awọn ara Egipti ati Farao ti se aiya wọn le? nigbati o ṣiṣẹ iyanu nla larin wọn, nwọn kò ha jẹ ki awọn enia na lọ bi? nwọn si lọ.

7. Nitorina ẹ ṣe kẹkẹ titun kan nisisiyi, ki ẹ si mu abo malu meji ti o nfi ọmu fun ọmọ, eyi ti kò ti igbà ajaga si ọrun ri, ki ẹ si so o mọ kẹkẹ́ na, ki ẹnyin ki o si mu ọmọ wọn kuro lọdọ wọn wá ile.

8. Ki ẹnyin ki o si gbe apoti Oluwa nì ka ori kẹkẹ̀ na, ki ẹnyin ki o si fi ohun elo wura wọnni ti ẹnyin dá fun u nitori ẹbọ ọrẹ irekọja, ninu apoti kan li apakan rẹ̀; ki ẹnyin rán a, yio si lọ.

9. Ki ẹ si kiyesi i, bi o ba lọ si ọ̀na agbegbe tirẹ̀ si Betṣemeṣi, a jẹ pe on na li o ṣe wa ni buburu yi: ṣugbọn bi kò ba ṣe bẹ̃, nigbana li awa o to mọ̀ pe, ki iṣe ọwọ́ rẹ̀ li o lù wa, ṣugbọn ẽṣi li o ṣe si wa.

10. Awọn ọkunrin na si ṣe bẹ̃: nwọn si mu abo malu meji; ti nfi ọmu fun ọmọ, nwọn si dè wọn mọ kẹkẹ́ na, nwọn si se ọmọ wọn mọ ile.

Ka pipe ipin 1. Sam 6