Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 30:13-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Dafidi si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ iṣe? ati nibo ni iwọ ti wá? On si wipe, ọmọ ara Egipti li emi iṣe, ọmọ-ọdọ ọkunrin kan ara Amaleki; oluwa mi si fi mi silẹ, nitoripe lati ijọ mẹta li emi ti ṣe aisan.

14. Awa si gbe ogun lọ siha gusu ti ara Keriti, ati si apa ti iṣe ti Juda, ati si iha gusu ti Kelebu; awa si kun Siklagi.

15. Dafidi si bi i lere pe, Iwọ le mu mi sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun yi lọ bi? On si wipe, Fi Ọlọrun bura fun mi, pe, iwọ kì yio pa mi, bẹ̃ni iwọ kì yio si fi mi le oluwa mi lọwọ; emi o si mu ọ sọkalẹ tọ̀ ẹgbẹ ogun na lọ.

16. O si mu u sọkalẹ, si wõ, nwọn si tànka ilẹ, nwọn njẹ, nwọn nmu, nwọn si njo, nitori ikogun pupọ ti nwọn ko lati ilẹ awọn Filistini wá, ati lati ilẹ Juda.

17. Dafidi si pa wọn lati afẹmọjumọ titi o fi di aṣalẹ ijọ keji: kò si si ẹnikan ti o là ninu wọn, bikoṣe irinwo ọmọkunrin ti nwọn gun ibakasiẹ ti nwọn si sa.

18. Dafidi si gba gbogbo nkan ti awọn ara Amaleki ti ko: Dafidi si gbà awọn obinrin rẹ̀ mejeji.

Ka pipe ipin 1. Sam 30