Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 30:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si bọ̀ si Siklagi ni ijọ kẹta, awọn ara Amaleki si ti kọlu iha ariwa, ati Siklagi, nwọn si ti kun u;

2. Nwọn si ko awọn obinrin ti mbẹ ninu rẹ̀ ni igbekun, nwọn kò si pa ẹnikan, ọmọde tabi agbà, ṣugbọn nwọn ko nwọn lọ, nwọn si ba ọ̀na ti nwọn lọ.

3. Dafidi ati awọn ọmọkunrin si wọ ilu, si wõ, a ti kun u; ati obinrin wọn, ati ọmọkunrin wọn ati ọmọbinrin wọn li a kó ni igbèkun lọ.

4. Dafidi ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ si gbe ohùn wọn soke, nwọn si sọkun titi agbara kò si si fun wọn mọ lati sọkun.

5. A si kó awọn aya Dafidi mejeji nigbèkun lọ, Ahinoamu ara Jesreeli, ati Abigaili aya, Nabali ara Karmeli.

6. Dafidi si banujẹ gidigidi, nitoripe awọn enia na si nsọ̀rọ lati sọ ọ li okuta, nitoriti inu gbogbo awọn enia na si bajẹ, olukuluku ọkunrin nitori ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati nitori ọmọ rẹ̀ obinrin: ṣugbọn Dafidi mu ara rẹ̀ li ọkàn le ninu Oluwa Ọlọrun rẹ̀.

7. Dafidi si wi fun Abiatari alufa, ọmọ Ahimeleki pe, Emi bẹ̀ ọ, mu efodu fun mi wá nihinyi. Abiatari si mu efodu na wá fun Dafidi.

8. Dafidi si bere lọdọ Oluwa wipe, Ki emi ki o lepa ogun yi bi? emi le ba wọn? O si da a lohùn pe, Lepa: nitoripe ni biba iwọ o ba wọn, ni gbigba iwọ o si ri wọn gbà.

9. Bẹni Dafidi ati ẹgbẹta ọmọkunrin ti mbẹ lọdọ rẹ̀ si lọ, nwọn si wá si ibi odo Besori, apakan si duro.

10. Ṣugbọn Dafidi ati irinwo ọmọkunrin lepa wọn: igba enia ti ãrẹ̀ mu, ti nwọn kò le kọja odò Besori si duro lẹhin.

11. Nwọn si ri ara Egipti kan li oko, nwọn si mu u tọ̀ Dafidi wá, nwọn si fun u li onjẹ, o si jẹ; nwọn si fun u li omi mu;

12. Nwọn si bùn u li akara eso ọpọtọ ati ṣiri ajara gbigbẹ meji: nigbati o si jẹ ẹ tan, ẹmi rẹ̀ si sọji: nitoripe ko jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò si mu omi ni ijọ mẹta li ọsan, ati li oru.

13. Dafidi si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ iṣe? ati nibo ni iwọ ti wá? On si wipe, ọmọ ara Egipti li emi iṣe, ọmọ-ọdọ ọkunrin kan ara Amaleki; oluwa mi si fi mi silẹ, nitoripe lati ijọ mẹta li emi ti ṣe aisan.

Ka pipe ipin 1. Sam 30