Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 26:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN ara Sifi si tọ̀ Saulu wá si Gibea, nwọn wipe, Ṣe Dafidi fi ara rẹ̀ pamọ nibi oke Hakila, eyi ti o wà niwaju Jeṣimoni?

2. Saulu si dide o si sọkalẹ lọ si ijù Sifi, ẹgbẹ̀dogun àṣayàn enia ni Israeli si pẹlu rẹ̀ lati wá Dafidi ni iju Sifi.

3. Saulu si pagọ rẹ̀ ni ibi oke Hakila ti o wà niwaju Jeṣimoni li oju ọ̀na. Dafidi si joko ni ibi iju na, o si ri pe Saulu ntẹle on ni iju na.

4. Dafidi si ran amí jade, o si mọ̀ nitõtọ pe Saulu mbọ̀.

5. Dafidi si dide, o si wá si ibi ti Saulu pagọ si: Dafidi si ri ibi ti Saulu gbe dubulẹ si, ati Abneri ọmọ Neri, olori ogun rẹ̀: Saulu si dubulẹ larin awọn kẹ̀kẹ́, awọn enia na si pagọ wọn yi i ka.

6. Dafidi si dahun, o si wi fun Ahimeleki ọkan ninu awọn ọmọ Heti, ati fun Abiṣai ọmọ Seruia arákùnrin Joabu, pe, Tani o ba mi sọkalẹ lọ sọdọ Saulu ni ibudo? Abiṣai si wipe, emi o ba ọ sọkalẹ lọ.

7. Bẹ̃ni Dafidi ati Abiṣai si tọ awọn enia na wá li oru: si wõ, Saulu dubulẹ o si nsun larin kẹkẹ, a si fi ọ̀kọ rẹ̀ gunlẹ ni ibi timtim rẹ̀: Abneri ati awọn enia na si dubulẹ yi i ka.

8. Abiṣai si wi fun Dafidi pe, Ọlọrun ti fi ọta rẹ le ọ lọwọ loni: njẹ, emi bẹ ọ, sa jẹ ki emi ki o fi ọ̀kọ gun u mọlẹ lẹ̃kan, emi ki yio gun u lẹ̃meji.

9. Dafidi si wi fun Abiṣai pe, Máṣe pa a: nitoripe tani le nawọ́ rẹ̀ si ẹni-ami-ororo Oluwa ki o si wà laijẹbi?

10. Dafidi si wipe, bi Oluwa ti mbẹ Oluwa yio pa a, tabi ọjọ rẹ̀ yio si pe ti yio kú, tabi on o sọkalẹ lọ si ibi ijà, a si ṣegbe nibẹ.

11. Oluwa má jẹ ki emi nà ọwọ́ mi si ẹni-àmi-ororo Oluwa: njẹ, emi bẹ ọ, mu ọ̀kọ na ti mbẹ nibi timtim rẹ̀, ati igo omi ki a si ma lọ.

12. Dafidi si mu ọ̀kọ na, ati igo omi na kuro nibi timtim Saulu: nwọn si ba ti wọn lọ, kò si si ẹnikan ti o ri i, tabi ti o mọ̀; kò si si ẹnikan ti o ji; gbogbo wọn si sùn; nitoripe orun àjika lati ọdọ Oluwa wá ti ṣubu lù wọn.

13. Dafidi si rekọja si iha keji, o si duro lori oke kan ti o jina rere; afo nla kan si wà lagbedemeji wọn:

14. Dafidi si kọ si awọn enia na, ati si Abneri ọmọ Neri wipe, Iwọ kò dahun, Abneri? Nigbana ni Abneri si dahun wipe, Iwọ tani npe ọba?

15. Dafidi si wi fun Abneri pe, Alagbara ọkunrin ki iwọ nṣe ndan? tali o si dabi iwọ ni Israeli? njẹ ẽṣe ti iwọ ko tọju ọba oluwa rẹ? nitori ẹnikan ninu awọn enia na ti wọle wá lati pa ọba oluwa rẹ.

Ka pipe ipin 1. Sam 26