Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 25:38-44 Yorùbá Bibeli (YCE)

38. O si ṣe lẹhin iwọn ijọ mẹwa, Oluwa lù Nabali, o si kú.

39. Dafidi si gbọ́ pe Nabali kú, o si wi pe, Iyin ni fun Oluwa ti o gbeja gigàn mi lati ọwọ́ Nabali wá, ti o si da iranṣẹ rẹ̀ duro lati ṣe ibi: Oluwa si yi ikà Nabali si ori on tikalarẹ̀. Dafidi si ranṣẹ, o si ba Abigaili sọ̀rọ lati mu u fi ṣe aya fun ara rẹ̀.

40. Awọn iranṣẹ Dafidi si lọ sọdọ Abigaili ni Karmeli, nwọn si sọ fun u pe, Dafidi rán wa wá si ọ lati mu ọ ṣe aya rẹ̀.

41. O si dide, o si dojubolẹ, o si wipe, Wõ, jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ ki o jẹ iranṣẹ kan lati ma wẹ ẹsẹ awọn iranṣẹ oluwa mi.

42. Abigaili si yara, o dide, o si gun kẹtẹkẹtẹ, awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ marun si tẹle e lẹhin; on si tẹle awọn iranṣẹ Dafidi, o si wa di aya rẹ̀.

43. Dafidi si mu Ahinoamu ti Jesreeli; awọn mejeji si jẹ aya rẹ̀.

44. Ṣugbọn Saulu ti fi Mikali ọmọ rẹ̀ obinrin, aya Dafidi, fun Falti ọmọ Laisi ti iṣe ara Gallimu.

Ka pipe ipin 1. Sam 25