Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 25:17-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Njẹ si ro o wò, ki o si mọ̀ eyiti iwọ o ṣe; nitoripe ati gbero ibi si oluwa wa, ati si gbogbo ile rẹ̀: on si jasi ọmọ Beliali ti a ko le sọ̀rọ fun.

18. Abigaili si yara, o si mu igba iṣu akara ati igo ọti-waini meji, ati agutan marun, ti a ti sè, ati oṣuwọn agbado yiyan marun, ati ọgọrun idi ajara, ati igba akara eso ọpọtọ, o si di wọn ru kẹtẹkẹtẹ.

19. On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Ma lọ niwaju mi; wõ, emi mbọ lẹhin nyin. Ṣugbọn on kò wi fun Nabali bale rẹ̀.

20. O si ṣe, bi o ti gun ori kẹtẹkẹtẹ, ti o si nsọkalẹ si ibi ikọkọ oke na, wõ, Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si nsọ-kalẹ, niwaju rẹ̀; on si wá pade wọn.

21. Dafidi si ti wipe, Njẹ lasan li emi ti pa gbogbo eyi ti iṣe ti eleyi mọ li aginju, ti ohunkohun kò si nù ninu gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀; on li o si fi ibi san ire fun mi yi.

22. Bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ ni ki Ọlọrun ki o ṣe si awọn ọta Dafidi, bi emi ba fi ẹnikẹni ti ntọ̀ sara ogiri silẹ ninu gbogbo eyi ti iṣe tirẹ̀ titi di imọlẹ owurọ.

23. Abigaili si ri Dafidi, on si yara, o sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ, o si dojubolẹ niwaju Dafidi, o si tẹ ara rẹ̀ ba silẹ.

24. O si wolẹ li ẹba ẹsẹ rẹ̀ o wipe, Oluwa mi, fi ẹ̀ṣẹ yi ya mi: ki o si jẹ ki iranṣẹbinrin rẹ, emi bẹ̀ ọ, sọ̀rọ leti rẹ, ki o si gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹbinrin rẹ.

25. Oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, má ka ọkunrin Beliali yi si, ani Nabali: nitoripe bi orukọ rẹ̀ ti jẹ bẹ̃li on na ri: Nabali li orukọ rẹ̀, aimoye si wà pẹlu rẹ̀; ṣugbọn emi iranṣẹbinrin rẹ kò ri awọn ọmọkunrin oluwa mi, ti iwọ rán.

26. Njẹ, oluwa mi, bi Oluwa ti wà lãye, ati bi ẹmi rẹ si ti wà làye, bi Oluwa si ti da ọ duro lati wá ta ẹjẹ silẹ, ati lati fi ọwọ́ ara rẹ gbẹsan; njẹ, ki awọn ọta rẹ, ati awọn ẹniti ngbero ibi si oluwa mi ri bi Nabali.

27. Njẹ eyi ni ẹbùn ti iranṣẹbinrin rẹ mu wá fun oluwa mi, jẹ ki a si fi fun awọn ọmọkunrin ti ntọ oluwa mi lẹhin.

28. Emi bẹ̀ ọ, fi irekọja iranṣẹbinrin rẹ ji i: nitori ti Oluwa yio sa ṣe ile ododo fun oluwa mi, nitori ogun Oluwa ni oluwa mi njà; a kò si ri ibi lọwọ rẹ ni gbogbo ọjọ rẹ.

29. Ọkunrin kan si dide lati ma lepa rẹ, ati lati ma wá ẹmi rẹ: ṣugbọn a o si di ẹmi oluwa mi ninu idi ìye lọdọ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹmi awọn ọta rẹ li a o si gbọ̀n sọnù gẹgẹ bi kànakana jade.

30. Yio si ṣe, Oluwa yio ṣe si oluwa mi gẹgẹ bi gbogbo ire ti o ti wi nipa tirẹ, yio si yan ọ li alaṣẹ lori Israeli.

31. Eyi ki yio si jasi ibinujẹ fun ọ, tabi ibinujẹ ọkàn fun oluwa mi, nitoripe iwọ ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ, tabi pe oluwa mi gbẹsan fun ara rẹ̀: ṣugbọn nigbati Oluwa ba ṣe ore fun oluwa mi, njẹ ranti iranṣẹbinrin rẹ.

32. Dafidi si wi fun Abigaili pe, Alabukun fun Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ran ọ loni yi lati pade mi.

33. Ibukun ni fun ọgbọn rẹ, alabukunfun si ni iwọ, ti o da mi duro loni yi lati wá ta ẹjẹ silẹ, ati lati fi ọwọ́ mi gbẹsan fun ara mi.

Ka pipe ipin 1. Sam 25