Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 24:2-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Saulu si mu ẹgbẹdogun akọni ọkunrin ti a yàn ninu gbogbo Israeli, o si lọ lati wá Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ lori okuta awọn ewurẹ igbẹ.

3. O si de ibi awọn agbo agutan ti o wà li ọ̀na, ihò kan si wà nibẹ, Saulu si wọ inu rẹ̀ lọ lati bo ẹsẹ rẹ̀: Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si mbẹ lẹba iho na.

4. Awọn ọmọkunrin Dafidi si wi fun u pe, Wõ, eyi li ọjọ na ti Oluwa wi fun ọ pe, Wõ, emi o fi ọta rẹ le ọ li ọwọ́, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi o ti tọ li oju rẹ. Dafidi si dide, o si yọ lọ ike eti aṣọ Saulu.

5. O si ṣe lẹhin eyi, aiya já Dafidi nitoriti on ke eti aṣọ Saulu.

6. On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Èwọ̀ ni fun mi lati ọdọ Oluwa wá bi emi ba ṣe nkan yi si oluwa mi, ẹniti a ti fi ami ororo Oluwa yàn, lati nàwọ́ mi si i, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa ni.

7. Dafidi si fi ọ̀rọ wọnyi da awọn ọmọkunrin rẹ̀ duro, kò si jẹ ki wọn dide si Saulu. Saulu si dide kuro ni iho na, o si ba ọ̀na rẹ̀ lọ.

8. Dafidi si dide lẹhin na, o si jade kuro ninu iho na, o si kọ si Saulu pe, Oluwa mi, ọba. Saulu si wo ẹhìn rẹ̀, Dafidi si doju rẹ̀ bo ilẹ, o si tẹriba fun u.

9. Dafidi si wi fun Saulu pe, Eha ti ṣe ti iwọ fi ngbọ́ ọ̀rọ awọn enia pe, Wõ, Dafidi nwá ẹmi rẹ?

Ka pipe ipin 1. Sam 24