Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 23:10-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Dafidi si wipe Oluwa Ọlọrun Israeli, lõtọ ni iranṣẹ rẹ ti gbọ́ pe Saulu nwá ọ̀na lati wá si Keila, lati wá fọ ilu na nitori mi.

11. Awọn agba ilu Keila yio fi mi le e lọwọ bi? Saulu yio ha sọkalẹ, gẹgẹ bi iranṣẹ rẹ ti gbọ́ bi? Oluwa Ọlọrun Israeli, emi bẹ̀ ọ, wi fun iranṣẹ rẹ. Oluwa si wipe, Yio sọkalẹ wá.

12. Dafidi si wipe, Awọn agbà ilu Keila yio fi emi ati awọn ọmọkunrin mi le Saulu lọwọ bi? Oluwa si wipe, Nwọn o fi ọ le wọn lọwọ.

13. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ ti wọn to ẹgbẹta enia si dide, nwọn lọ kuro ni Keila, nwọn si lọ si ibikibi ti nwọn le lọ. A si wi fun Saulu pe, Dafidi ti sa kuro ni Keila; ko si lọ si Keila mọ.

14. Dafidi si ngbe ni aginju, nibiti o ti sa pamọ si, o si ngbe nibi oke-nla kan li aginju Sifi. Saulu si nwá a lojojumọ, ṣugbọn Ọlọrun ko fi le e lọwọ.

15. Dafidi si ri pe, Saulu ti jade lati wá ẹmi on kiri: Dafidi si wà li aginju Sifi ninu igbo kan.

16. Jonatani ọmọ Saulu si dide, o si tọ Dafidi lọ ninu igbo na, o si gba a ni iyanju nipa ti Ọlọrun.

17. On si wi fun u pe, Máṣe bẹru: nitori ọwọ́ Saulu baba mi kì yio tẹ̀ ọ: iwọ ni yio jọba lori Israeli, emi ni yio si ṣe ibikeji rẹ; Saulu baba mi mọ̀ bẹ̃ pẹlu.

18. Awọn mejeji si ṣe adehun niwaju Oluwa; Dafidi si joko ninu igbo na. Jonatani si lọ si ile rẹ̀.

19. Awọn ara Sifi si goke tọ Saulu wá si Gibea, nwọn si wipe, Ṣe Dafidi ti fi ara rẹ̀ pamọ sọdọ wa ni ibi ti o to sa pamọ si ni igbo, ni oke Hakila, ti o wà niha gusu ti Jeṣimoni?

20. Njẹ nisisiyi, Ọba, sọkalẹ wá gẹgẹ bi gbogbo ifẹ ti o wà li ọkàn rẹ lati sọkalẹ; ipa ti awa ni lati fi i le ọba lọwọ.

Ka pipe ipin 1. Sam 23