Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 23:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NWỌN si wi fun Dafidi pe, Sa wõ awọn ara Filistia mba ara Keila jagun, nwọn si jà ilẹ ipakà wọnni li ole.

2. Dafidi si bere lọdọ Oluwa pe, Ki emi ki o lọ kọlu awọn ara Filistia wọnyi bi? Oluwa si wi fun Dafidi pe. Lọ, ki o si kọlu awọn ara Filistia ki o si gbà Keila silẹ.

3. Awọn ọmọkunrin ti o wà lọdọ Dafidi si wi fun u pe, Wõ, awa mbẹ̀ru nihinyi ni Juda; njẹ yio ti ri nigbati awa ba de Keila lati fi oju ko ogun awọn ara Filistia?

4. Dafidi si tun bere lọdọ Oluwa. Oluwa si da a lohùn, o si wipe, Dide, ki o sọkalẹ lọ si Keila, nitoripe emi o fi awọn ara Filistia na le ọ lọwọ.

5. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si lọ si Keila, nwọn si ba awọn ara Filistia jà, nwọn si ko ohun ọsìn wọn, nwọn si fi iparun nla pa wọn. Dafidi si gbà awọn ara Keila silẹ.

6. O si ṣe, nigbati Abiatari ọmọ Ahimeleki fi sa tọ Dafidi lọ ni Keila, o sọkalẹ ton ti efodu kan lọwọ rẹ̀,

7. A si sọ fun Saulu pe, Dafidi wa si Keila. Saulu si wipe, Ọlọrun ti fi i le mi lọwọ; nitoripe a ti dí i mọ tan, nitori o wọ inu ilu ti o ni ilẹkun ati ikere.

8. Saulu si pe gbogbo awọn enia na jọ si ogun, lati sọkalẹ lọ si Keila, lati ká Dafidi mọ ati awọn ọmọkunrin rẹ̀.

9. Dafidi si mọ̀ pe Saulu ti gbèro buburu si on; o si wi fun Abiatari alufa na pe, Mu efodu na wá nihinyi.

Ka pipe ipin 1. Sam 23