Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 21:4-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Alufa na si da Dafidi lohùn o si wipe, Kò si akara miran li ọwọ́ mi bikoṣe akara mimọ́; bi awọn ọmọkunrin ba ti pa ara wọn mọ kuro lọdọ obinrin.

5. Dafidi si da alufa na lohùn, o si wi fun u pe, Nitotọ a ti pa ara wa mọ kuro lọdọ obinrin lati iwọn ijọ mẹta wá, ti emi ti jade; gbogbo nkan awọn ọmọkunrin na li o mọ́, ati akara na si wa dabi akara miran, ye e pãpã nigbati o jẹ pe omiran wà ti a yà si mimọ́ loni ninu ohun elo na.

6. Bẹ̃ni alufa na si fi akara mimọ́ fun u; nitoriti kò si akara miran nibẹ bikoṣe akara ifihan ti a ti ko kuro niwaju Oluwa, lati fi akara gbigbona sibẹ li ọjọ ti a ko o kuro.

7. Ọkunrin kan ninu awọn iranṣẹ Saulu si mbẹ nibẹ li ọjọ na, ti a ti da duro niwaju Oluwa; orukọ rẹ̀ si njẹ Doegi, ara Edomu olori ninu awọn darandaran Saulu.

8. Dafidi si tun wi fun Ahimeleki pe, Kò si ọ̀kọ tabi idà lọwọ rẹ nihin? nitoriti emi kò mu idà mi, bẹ̃li emi kò mu nkan ijà mi lọwọ, nitoripe iṣẹ ọba na jẹ́ iṣẹ ikanju.

9. Alufa na si wipe, idà Goliati ara Filistini ti iwọ pa li afonifoji Ela ni mbẹ, wõ, a fi aṣọ kan wé e lẹhin Efodu; bi iwọ o ba mu eyini, mu u; kò si si omiran nihin mọ bikoṣe ọkanna. Dafidi si wipe, Kò si eyiti o dabi rẹ̀, fun mi.

10. Dafidi si dide, o si sa ni ijọ na niwaju Saulu, o si lọ sọdọ Akiṣi, ọba Gati.

11. Awọn iranṣẹ Akiṣi si wi fun u pe, Ṣe eyiyi ni Dafidi ọba ilẹ na? nwọn kò ha ti da ti nwọn si gberin nitori rẹ̀ ni ijo, pe, Saulu pa ẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbãrun tirẹ̀?

Ka pipe ipin 1. Sam 21