Alufa na si da Dafidi lohùn o si wipe, Kò si akara miran li ọwọ́ mi bikoṣe akara mimọ́; bi awọn ọmọkunrin ba ti pa ara wọn mọ kuro lọdọ obinrin.