Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 20:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. DAFIDI si sa kuro ni Naoti ti Rama, o si wá, o si wi li oju Jonatani pe, Kili emi ṣe? kini ìwa buburu mi, ati kili ẹ̀ṣẹ mi li oju baba rẹ, ti o fi nwá ọ̀na ati pa mi.

2. On si wi fun u pe, Ki a má ri i, iwọ kì yio kú: wõ, baba mi ki yio ṣe nkan nla tabi kekere lai sọ ọ li eti mi, njẹ, esi ti ṣe ti baba mi yio fi pa nkan yi mọ fun mi? nkan na kò ri bẹ̃.

3. Dafidi si tun bura, pe, Baba rẹ ti mọ̀ pe, emi ri oju rere li ọdọ rẹ; on si wipe, Máṣe jẹ ki Jonatani ki o mọ̀ nkan yi, ki o má ba binu: ṣugbọn nitotọ, bi Oluwa ti wà, ati bi ọkàn rẹ si ti wà lãye, iṣisẹ̀ kan ni mbẹ larin emi ati ikú.

4. Jonatani si wi fun Dafidi pe, Ohunkohun ti ọkàn rẹ ba nfẹ, wi, emi o si ṣe e fun ọ.

5. Dafidi si wi fun Jonatani pe, Wõ, li ọla li oṣu titun, emi kò si gbọdọ ṣe alai ba ọba joko lati jẹun; ṣugbọn jẹ ki emi ki o lọ, ki emi si fi ara pamọ li oko titi yio fi di aṣalẹ ijọ kẹta.

6. Bi o ba si ṣepe baba rẹ fẹ mi kù, ki o si wi fun u pe, Dafidi bẹ̀ mi lati sure lọ si Betlehemu ilu rẹ̀: nitoripe ẹbọ ọdun kan kò nibẹ fun gbogbo idile na.

7. Bi o ba wipe, O dara, alafia mbẹ fun iranṣẹ rẹ: ṣugbọn bi o ba binu pupọ, njẹ ki iwọ ki o mọ̀ daju pe buburu ni o nrò ninu rẹ̀.

8. Iwọ o si ṣe ore fun iranṣẹ rẹ, nitoripe iwọ ti mu iranṣẹ rẹ wọ inu majẹmu Oluwa pẹlu rẹ; ṣugbọn bi ìwa buburu ba mbẹ li ọwọ mi, iwọ tikararẹ pa mi; ẽṣe ti iwọ o fi mu mi tọ baba rẹ lọ?

9. Jonatani si wipe, Ki eyini ki o jina si ọ: nitoripe bi emi ba mọ̀ daju pe baba mi npete ibi ti yio wá sori rẹ, njẹ emi le iṣe alaisọ ọ fun ọ bi?

10. Nigbana ni Dafidi wi fun Jonatani pe, Tani yio sọ fun mi? tabi yio ti ri bi baba rẹ ba si fi ìjãnu da ọ lohùn.

11. Jonatani si wi fun Dafidi pe, Wá, jẹ ki a jade lọ si pápá. Awọn mejeji si jade lọ si pápá.

12. Jonatani si wi fun Dafidi pe, Oluwa Ọlọrun Israeli, nigbati mo ba si lu baba mi li ohùn gbọ́ li ọla tabi li ọtunla, si wõ, bi ire ba wà fun Dafidi, ti emi kò ba si ranṣẹ si ọ, ti emi kò si sọ ọ li eti rẹ.

13. Ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ si Jonatani: ṣugbọn bi o ba si ṣe pe o wu baba mi lati ṣe buburu si ọ, emi o si sọ ọ li eti rẹ, emi o si jẹ ki o lọ, iwọ o si lọ li alafia, ki Oluwa ki o si pẹlu rẹ gẹgẹ bi o ti wà pẹlu baba mi.

Ka pipe ipin 1. Sam 20