11. Elkana si lọ si Rama si ile rẹ̀. Ọmọ na si nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli alufa.
12. Awọn ọmọ Eli si jẹ ọmọ Beliali; nwọn kò mọ̀ Oluwa.
13. Iṣe awọn alufa pẹlu awọn enia ni, nigbati ẹnikan ba ṣe irubọ, iranṣẹ alufa a de, nigbati ẹran na nho lori iná, ti on ti ọpa-ẹran oniga mẹta li ọwọ́ rẹ̀.
14. On a si fi gun inu apẹ, tabi kẹtili tabi òdu, tabi ikokò, gbogbo eyi ti ọpa-ẹran oniga na ba mu wá oke, alufa a mu u fun ara rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn nṣe si gbogbo Israeli ti o wá si ibẹ̀ ni Ṣilo.
15. Pẹlu ki nwọn ki o to sun ọra na, iranṣẹ alufa a de, a si wi fun ọkunrin ti on ṣe irubọ pe, Fi ẹran fun mi lati sun fun alufa; nitoriti kì yio gba ẹran sisè lọwọ rẹ, bikoṣe tutù.
16. Ọkunrin na si wi fun u pe, Jẹ ki wọn sun ọra na nisisiyi, ki o si mu iyekiye ti ọkàn rẹ ba fẹ; nigbana li o da a lohun pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn ki iwọ ki o fi i fun mi nisisiyi: bikoṣe bẹ̃, emi o fi agbara gbà a.
17. Ẹṣẹ awọn ọdọmọkunrin na si tobi gidigidi niwaju Oluwa: nitoriti enia korira ẹbọ Oluwa.
18. Ṣugbọn Samueli nṣe iranṣẹ niwaju Oluwa, o ṣe ọmọde, ti a wọ̀ ni efodi ọgbọ.
19. Pẹlupẹlu iya rẹ̀ da aṣọ ileke penpe fun u, a ma mu fun u wá lọdọdun, nigbati o ba bá ọkọ rẹ̀ goke wá lati ṣe irubọ ọdun.
20. Eli sure fun Elkana ati aya rẹ̀ pe ki Oluwa ki o ti ara obinrin yi fun ọ ni iru-ọmọ nipa ibere na ti o bere lọdọ Oluwa. Nwọn si lọ si ile wọn.
21. Oluwa si boju wo Hanna, o si loyun, o bi ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin meji. Samueli ọmọ na si ndagbà niwaju Oluwa.
22. Eli si di arugbo gidigidi, o si gbọ́ gbogbo eyi ti awọn ọmọ rẹ̀ ṣe si gbogbo Israeli; ati bi nwọn ti ima ba awọn obinrin sùn, ti nwọn ma pejọ li ẹnu ọ̀na agọ ajọ.
23. O si wi fun wọn pe, Etiri ti emi fi ngbọ́ iru nkan bẹ̃ si nyin? nitoriti emi ngbọ́ iṣe buburu nyin lati ọdọ gbogbo enia yi wá.