Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 17:39-53 Yorùbá Bibeli (YCE)

39. Dafidi si di ida rẹ̀ mọ ihamọra rẹ̀, on si gbiyanju lati lọ, on kò sa iti dan a wò. Dafidi si wi fun Saulu pe, Emi kò le ru wọnyi lọ, nitoripe emi kò idan a wò. Dafidi si tu wọn kuro li ara rẹ̀.

40. On si mu ọpa rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, o si ṣà okuta marun ti o jọlọ̀ ninu odò, o si fi wọn sinu apò oluṣọ agutan ti o ni, ani sinu asùwọn: kànakana rẹ̀ si wà li ọwọ́ rẹ̀; o si sunmọ Filistini na.

41. Filistini na si mbọ̀, o si nsunmọ Dafidi; ati ọkunrin ti o rù awà rẹ̀ si mbọ̀ niwaju rẹ̀.

42. Nigbati Filistini na si wò, ti o si ri Dafidi, o ṣata rẹ̀: nitoripe ọdọmọdekunrin ni iṣe, o pọn, o si ṣe arẹwa enia.

43. Filistini na si wi fun Dafidi pe, Emi ha nṣe aja bi, ti iwọ fi mu ọpá tọ̀ mi wá? Filistini na si fi Dafidi re nipa awọn ọlọrun rẹ̀.

44. Filistini na si wi fun Dafidi pe, Mã bọ̀; emi o si fi ẹran ara rẹ fun awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati fun awọn ẹranko papa.

45. Dafidi si wi fun Filistini na pe, Iwọ mu idà, ati ọ̀kọ, ati awà tọ̀ mi wá; ṣugbọn emi tọ̀ ọ wá li orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun ogun Israeli ti iwọ ti gàn.

46. Loni yi li Oluwa yio fi iwọ le mi lọwọ́, emi o pa ọ, emi o si ke ori rẹ kuro li ara rẹ; emi o si fi okú ogun Filistini fun ẹiyẹ oju ọrun loni yi, ati fun ẹranko igbẹ; gbogbo aiye yio si mọ̀ pe, Ọlọrun wà fun Israeli.

47. Gbogbo ijọ enia yio si mọ̀ daju pe, Oluwa kò fi ida on ọ̀kọ gbà ni la: nitoripe ogun na ti Oluwa ni, yio si fi ọ le wa lọwọ.

48. O si ṣe, nigbati Filistini na dide, ti o nrìn, ti o si nsunmọ tosí lati pade Dafidi, Dafidi si yara, o si sure si ogun lati pade Filistini na.

49. Dafidi si fi ọwọ́ rẹ̀ si inu apò, o si mu okuta kan lati ibẹ̀ wá, o si fì i, o si bà Filistini na niwaju, okuta na si wọ inu agbari rẹ̀ lọ, o si ṣubu dojubolẹ.

50. Bẹ̃ni Dafidi si fi kànakàna on okuta ṣẹgun Filistini na, o si bori Filistini na, o si pa a; ṣugbọn idà ko si lọwọ Dafidi.

51. Dafidi si sure, o si duro lori Filistini na, o si mu ida rẹ̀, o si fà a yọ ninu akọ̀ rẹ̀, o si pa a, o si fi idà na bẹ́ ẹ li ori. Nigbati awọn Filistini si ri pe akikanju wọn kú, nwọn si sa.

52. Awọn ọkunrin Israeli ati ti Juda si dide, nwọn si ho yè, nwọn si nle awọn Filistini lọ, titi nwọn fi de afonifoji kan, ati si ojubode Ekronu. Awọn ti o gbọgbẹ ninu awọn Filistini si ṣubu lulẹ li ọ̀na Ṣaaraimu, ati titi de Gati, ati Ekronu.

53. Awọn ọmọ Israeli si pada lati ma lepa awọn Filistini, nwọn si ba budo wọn jẹ.

Ka pipe ipin 1. Sam 17