Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 17:34-46 Yorùbá Bibeli (YCE)

34. Dafidi si wi fun Saulu pe, Nigbati iranṣẹ rẹ nṣọ agutan baba rẹ̀, kiniun kan si wá, ati amọtẹkun kan, o si gbe ọdọ agutan kan lati inu agbo.

35. Mo si jade tọ̀ ọ, mo si lù u, mo si gbà a kuro li ẹnu rẹ̀: nigbati o si dide si mi, mo gbá irugbọ̀n rẹ̀ mu, mo si lù u, mo si pa a.

36. Iranṣẹ rẹ pa ati kiniun ati amọtẹkun na: alaikọla Filistini yi yio si dabi ọkan ninu wọn, nitoripe on ti pe ogun Ọlọrun alãye ni ijà.

37. Dafidi si wipe, Oluwa ti o gbà mi lọwọ́ kiniun ati lọwọ́ amọtẹkun, on na ni yio gbà mi lọwọ́ Filistini yi. Saulu si wi fun Dafidi pe, Lọ, Oluwa yio si pẹlu rẹ.

38. Saulu si fi gbogbo ihamọra ogun rẹ̀ wọ̀ Dafidi, o si fi ibori idẹ kan bò o li ori; o si fi ẹwu ti a fi irin adarọ pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe wọ̀ ọ.

39. Dafidi si di ida rẹ̀ mọ ihamọra rẹ̀, on si gbiyanju lati lọ, on kò sa iti dan a wò. Dafidi si wi fun Saulu pe, Emi kò le ru wọnyi lọ, nitoripe emi kò idan a wò. Dafidi si tu wọn kuro li ara rẹ̀.

40. On si mu ọpa rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, o si ṣà okuta marun ti o jọlọ̀ ninu odò, o si fi wọn sinu apò oluṣọ agutan ti o ni, ani sinu asùwọn: kànakana rẹ̀ si wà li ọwọ́ rẹ̀; o si sunmọ Filistini na.

41. Filistini na si mbọ̀, o si nsunmọ Dafidi; ati ọkunrin ti o rù awà rẹ̀ si mbọ̀ niwaju rẹ̀.

42. Nigbati Filistini na si wò, ti o si ri Dafidi, o ṣata rẹ̀: nitoripe ọdọmọdekunrin ni iṣe, o pọn, o si ṣe arẹwa enia.

43. Filistini na si wi fun Dafidi pe, Emi ha nṣe aja bi, ti iwọ fi mu ọpá tọ̀ mi wá? Filistini na si fi Dafidi re nipa awọn ọlọrun rẹ̀.

44. Filistini na si wi fun Dafidi pe, Mã bọ̀; emi o si fi ẹran ara rẹ fun awọn ẹiyẹ oju ọrun, ati fun awọn ẹranko papa.

45. Dafidi si wi fun Filistini na pe, Iwọ mu idà, ati ọ̀kọ, ati awà tọ̀ mi wá; ṣugbọn emi tọ̀ ọ wá li orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun ogun Israeli ti iwọ ti gàn.

46. Loni yi li Oluwa yio fi iwọ le mi lọwọ́, emi o pa ọ, emi o si ke ori rẹ kuro li ara rẹ; emi o si fi okú ogun Filistini fun ẹiyẹ oju ọrun loni yi, ati fun ẹranko igbẹ; gbogbo aiye yio si mọ̀ pe, Ọlọrun wà fun Israeli.

Ka pipe ipin 1. Sam 17