Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 17:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN Filistini si gbá ogun wọn jọ si oju ijà, nwọn si gba ara wọn jọ si Ṣoko, ti iṣe ti Juda, nwọn si do si Ṣoko ati Aseka, ni Efesdammimi.

2. Saulu ati awọn enia Israeli si gbá ara wọn jọ pọ̀, nwọn si do ni afonifoji Ela, nwọn si tẹ́ ogun de awọn Filistini.

3. Awọn Filistini si duro lori oke kan li apa kan, Israeli si duro lori oke kan li apa keji: afonifoji kan sì wa larin wọn.

4. Akikanju kan si jade lati ibudo awọn Filistini wá, orukọ rẹ̀ ama jẹ Goliati, ara Gati, ẹniti giga rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹfa ati ibu atẹlẹwọ kan.

5. On si ni akoro idẹ kan li ori rẹ̀, o si wọ̀ ẹ̀wu kan ti a fi idẹ pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọn ẹwu na si jẹ ẹgbẹdọgbọn Ṣekeli idẹ.

6. On si ni kobita idẹ li ẹsẹ rẹ̀, ati apata idẹ kan larin ejika rẹ̀.

7. Ọpa ọ̀kọ rẹ̀ si dabi igi awọn awunṣọ, ati ori ọ̀kọ rẹ̀ si jẹ ẹgbẹta oṣuwọn sekeli irin: ẹnikan ti o ru awà kan si nrin niwaju rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. Sam 17