Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 14:45-52 Yorùbá Bibeli (YCE)

45. Awọn enia si wi fun Saulu pe, Jonatani yio kú, ti o ṣe igbala nla yi ni Israeli? ki a má ri i; bi Oluwa ti wà, ọkan ninu irun ori rẹ̀ kì yio bọ́ silẹ; nitoripe o ba Ọlọrun ṣiṣẹ pọ̀ loni. Bẹ̃li awọn enia si gbà Jonatani silẹ, kò si kú.

46. Saulu si ṣiwọ ati ma lepa awọn Filistini: Awọn Filistini si lọ si ilu wọn.

47. Saulu si jọba lori Israeli; o si bá gbogbo awọn ọta rẹ̀ jà yika, eyini ni Moabu ati awọn ọmọ Ammoni, ati Edomu, ati awọn ọba Soba ati awọn Filistini: ati ibikibi ti o yi si, a bà wọn ninu jẹ.

48. O si ko ogun jọ, o si kọlu awọn Amaleki, o si gbà Israeli silẹ lọwọ awọn ti o nkó wọn.

49. Awọn ọmọ Saulu si ni Jonatani, ati Iṣui, ati Malkiṣua; ati orukọ ọmọbinrin rẹ̀ mejeji si ni wọnyi; orukọ akọbi ni Merabu, ati orukọ aburo ni Mikali:

50. Ati orukọ aya Saulu ni Ahinoamu, ọmọbinrin Ahimaasi, ati orukọ olori ogun rẹ̀ ni Abneri ọmọ Neri arakunrin baba Saulu.

51. Kiṣi si ni baba Saulu; ati Neri ni baba Abneri ọmọ Abieli.

52. Ogun na si le si awọn Filistini ni gbogbo ọjọ Saulu: bi Saulu ba ri ẹnikan ti o li agbara, tabi akikanju ọkunrin, a mu u sọdọ rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. Sam 14