Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 14:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe li ọjọ kan, Jonatani ọmọ Saulu si wi fun ọdọmọkunrin ti o nru ihamọra rẹ̀, pe, Wá, jẹ ki a rekọja lọ si ibudo-ogun awọn Filistini ti o wà niha keji. Ṣugbọn on kò sọ fun baba rẹ̀.

2. Saulu si duro ni iha ipinlẹ Gibea labẹ igi ìbo eyi ti o wà ni Migronu: awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ to iwọn ẹgbẹta ọkunrin.

3. Ahia ọmọ Ahitubu, arakunrin Ikabodu ọmọ Finehasi, ọmọ Eli, alufa Oluwa ni Ṣilo, ti nwọ̀ Efodu. Awọn enia na kò si mọ̀ pe Jonatani ti lọ.

4. Larin meji ọ̀na wọnni, eyi ti Jonatani ti nwá lati lọ si ile ọmọ-ogun olodi ti Filistini, okuta mimú kan wà li apa kan, okuta mímú kan si wà li apa keji: orukọ ekini si njẹ Bosesi, orukọ ekeji si njẹ Sene.

5. Ṣonṣo okuta ọkan wà ni ariwa kọju si Mikmaṣi, ti ekeji si wà ni gusù niwaju Gibea.

6. Jonatani wi fun ọdọmọdekunrin ti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Wá, si jẹ ki a lọ si budo-ogun awọn alaikọla yi: bọya Oluwa yio ṣiṣẹ fun wa: nitoripe kò si idiwọ fun Oluwa lati fi pipọ tabi diẹ gba là.

7. Ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ na wi fun u pe, Ṣe gbogbo eyi ti o mbẹ li ọkàn rẹ: ṣe bi o ti tọ́ li ọkàn rẹ; wõ, emi wà pẹlu rẹ gẹgẹ bi ti ọkàn rẹ.

8. Jonatani si wi pe, Kiye si i, awa o rekọja sọdọ awọn ọkunrin wọnyi, a o si fi ara wa hàn fun wọn.

Ka pipe ipin 1. Sam 14