Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 12:7-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Njẹ nisisiyi ẹ duro jẹ, ki emi ki o le ba nyin sọ̀rọ niwaju Oluwa niti gbogbo iṣẹ ododo Oluwa, eyi ti on ti ṣe fun nyin ati fun awọn baba nyin.

8. Nigbati Jakobu wá si Egipti, ti awọn baba kigbe pe Oluwa, Oluwa si rán Mose ati Aaroni, awọn ẹniti o mu awọn baba nyin ti ilẹ Egypti jade wá, o si mu wọn joko nihinyi.

9. Nwọn si gbagbe Oluwa Ọlọrun wọn, o si tà wọn si ọwọ́ Sisera, olori ogun Hasori, ati si ọwọ́ awọn Filistini, ati si ọwọ́ ọba Moabu, nwọn si ba wọn jà.

10. Nwọn si kigbe pe Oluwa, nwọn si wipe, Awa ti dẹsẹ̀, nitoripe awa ti kọ̀ Oluwa silẹ, awa si ti nsin Baalimu ati Aṣtaroti: ṣugbọn nisisiyi, gba wa lọwọ́ awọn ọta wa, awa o si sìn ọ.

11. Oluwa si ran Jerubbaali, ati Bedani, ati Jefta ati Samueli, nwọn si gbà nyin lọwọ́ awọn ọta nyin niha gbogbo, ẹnyin si joko li alafia.

Ka pipe ipin 1. Sam 12